Faith Adebọla, Eko
Ọjọ gbogbo ni t’ole, ọjọ kan ni tolohun. Ilẹ ọjọ kan ọhun lo mọ ba Ọlawale Samusudeen, ẹni ọdun mọkandilọgbọn to ko sakolo awọn ọlọpaa lalẹ Ọjọruu, ọjọ ki-in-ni, oṣu kẹsan-an yii, nibi to ti n ja oniṣọọbu kan lole.
Ṣọọbu olowo nla kan to wa ni Opopona Eric Moore, ni iyana ọna Eric Moore, laduugbo Bọde Thomas, ni Surulere, la gbọ pe afurasi ọdaran naa ti n ko wọn lẹru lọwọ, oun nikan kọ lo lọ sibẹ, o pada jẹwọ pe awọn meji mi-in wa nitosi ti iṣẹ adigunjale jọ pa awọn pọ, awọn jọ ṣe ọpureṣan naa ni.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Adekunle Ajiṣebutu, to jẹ k’ALAROYE gbọ nipa iṣẹlẹ yii sọ pe nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ ibi wọn lọwọ lawọn ọlọpaa to n patiroolu ti kọja ninu ọkọ wọn, lọkunrin to n taja ni ṣọọbu naa ba figbe ta, ariwo ‘ole, ole’ yii lo mu kawọn ọlọpaa bẹ silẹ ninu ọkọ wọn, wọn si sare sibi tiṣẹlẹ naa ti n waye.
Wọn ni gbara tawọn gbewiri ẹda yii foju gan-an-ni awọn ọlọpaa lawọn naa ba ẹsẹ wọn sọrọ, meji ninu wọn sa lọ, ọkada ti wọn gbe wa ni wọn fi ja pa, Ọlawale lọwọ tẹ, oun naa si lolori ikọ adigunjale ọhun.
Lara nnkan ija ti wọn ka mọ ọn lọwọ ni ibọn ibilẹ kan ti ọta wa ninu rẹ, katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin mẹta, oogun abẹnu gọngọ ati ọbẹ aṣooro kan.
Nigba ti wọn wọ ọ de teṣan ọlọpaa, Ajiṣebutu ni afurasi ọdaran naa jẹwọ pe agbegbe Bọde Thomas lawọn ti n digunjale, o loun ra ibọn ti wọn ba lọwọ oun ni, agbegbe Ikorodu lo ni wọn ti ta a foun.
Ṣa, Kọmiṣanna awọn ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti ni ki wọn taari Ọlawale sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, lẹyẹ-o-sọka lo si ti de ọdọ wọn.
Wọn l’Odumosu sọ pe awọn maa foju ẹ bale-ẹjọ laipẹ tiwadii ba ti pari.