Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Ẹti, Furaidee, ni ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ri ọkọ ajagbe agbepo kan gba lọwọ awọn to n ji epo bẹtiro ni abule Afọn, Laduba, nijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara, ti awọn to ji epo ọhun si sa lọ.
Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ ẹsọ alaabo ọhun nipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi, fi sita ni ọjọ Ẹti, Furaidee, lo ti sọ pe awọn to n lọọ bẹ ọpa epo naa fere ge e nigba ti wọn kẹẹfin ẹsọ alaabo naa ni oru ọjọ Furaidee, lakooko ti wọn n ṣiṣẹ ibi wọn lọwọ. Niṣe ni ọkọ tanka agbepo to gbe epo lita ẹgbẹrun lọna mẹtalelọgbọn (33,000 litres), yii ṣubu lulẹ lasiko ti wọn n gbinyanju lati sa lọ.
Ọga agba ajọ ọhun nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Makinde, ti waa ṣeleri pe ọwọ ajọ naa yoo tẹ awọn ọdaran yii laipẹ, ti wọn yoo si foju kata ofin, ti ajọ NSCDC yoo si ri i daju pe wọn daabo bo gbogbo dukia ijọba nipinlẹ Kwara ati gbogbo agbegbe rẹ.