Faith Adebọla
Inu ọfọ ni gbajugbaja ajafẹtọọ ọmọniyan ati oniroyin ẹrọ ayelujara Sahara Reporters, Ọmọyele Ṣoworẹ, wa lasiko yii, latari bawọn agbebọn kan ti wọn fura pe Fulani darandaran ni wọn ṣe rẹbuu ọkọ ti aburo rẹ, Ọlajide Ṣoworẹ, wa lowurọ ọjọ Abamẹta, Satide yii, ti wọn si yinbọn pa a bii ẹran.
Ninu alaye ti Ọmọyẹle Ṣoworẹ funra ẹ ṣe lori iṣẹlẹ buruku ọhun, o kọ ọ sori atẹ ayelujara rẹ pe:
“Ha, wọn ti pa aburo mi to tẹle mi gan-an o, Felix Ọlajide Ṣoworẹ, oni yii lawọn afurasi darandaran ti wọn n jiiyan gbe yinbọn fun un nitosi ilu Ọkada, nipinlẹ Edo, nigba to n dari rele lati Fasiti Igbinedion nibi to ti n kawe nipa imọ apoogun (famasi).
Ẹda n da ẹda ẹgbẹ ẹ loro, ẹda n gbẹmi lẹnu ẹda ẹgbẹ ẹ gidi. Sun bii akọni o, “Dokita Mamiye!”
Soworẹ tun ṣalaye pe ọga ọlọpaa teṣan Ọkada lo tufọ iṣẹlẹ naa fun mọlẹbi awọn nigba ti ikọ wọn sare lọ sibi iṣẹlẹ ọhun. O ni wọn ko ba awọn amookunṣika ẹda naa nibẹ mọ, wọn ti sa lọ.
Ṣaaju asiko yii lawọn ọdọ atawọn obinrin to wa niluu Ọkada ati agbegbe rẹ ti n pe akiyesi ijọba si ọṣẹ tawọn agbebọn, ajinigbe atawọn janduku darandaran n ṣe lagbegbe ọhun, wọn si ṣewọde lori iṣoro ọhun ninu oṣu keji, ọdun yii, lati ke sijọba ko ran wọn lọwọ.
Ọmọyele Ṣoworẹ tun daro oloogbe naa, o sọ pe: “Iwọ, oorun to ni ipilẹ, to n mu ki inu gbogbo eeyan maa dun. Iṣẹlẹ yii maa tubọ jẹ ki idajọ wọn ya kankan ni.”