Faith Adebọla
Odu ni Sunday Igboho, ki i ṣaimọ foloko. Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho Ooṣa, to ti wa lahaamọ orileede Olominira Bẹnẹ lati bii oṣu meji sẹyin, ba Ọgbẹni Adekunle Arẹmu, ọmọ Yoruba to fi Bẹnẹ ṣebugbe, sọrọ lori foonu nipa bi ẹjọ rẹ lọhun-un ṣe n lọọ. O sọ nipa ohun to mu inu bi oun nigba ti ọkan ninu awọn lọọya rẹ ṣabẹwo si i laipẹ yii, o si sọ ero rẹ lori ijangbara ilẹ Yoruba to gun le.
ALAROYE mu diẹ lara ohun ti wọn sọ wa fun yin.
Sunday Igboho: Baba, mo fi Ọlọrun to ni mi, mo fi bura fun yin, mi o ki i purọ, ẹ le beere mi lọwọ Baba mi, Ajani Bello, wọn aa sọ fun yin, emi o ki i purọ, bi mo ṣe sọrọ kọ niyẹn, mi o tiẹ sọrọ lile kankan, mo kan sọ pe lọọya, mo ṣi wa nibi, mo n duro o, mo ti lo to iṣẹju mẹẹẹdogun lori iduro yẹn, awọn to n ba sọrọ yẹn kọ lo wa wa nao, to ba sọ fun wọn pe ‘ẹ jọọ, ẹ fun mi niṣẹju meji, ẹ jẹ ki n sare da onibaara mi lohun, ma a pada wa, a o maa sọrọ wa lọ, wọn o ni i binu’. Ṣebi awọn naa mọ pe emi lo tori ẹ wa, bẹt ẹ kan fi mi sori iduro nibẹ yẹn, awọn tẹ ẹ n ba sọrọ, mi o mọ wọn ri, mi o gbọ ede wọn ri, ko daa bẹẹ nao.
Baba, nigba ti wọn de ti wọn ni lọọya fẹẹ ri mi, tori mi o mọ lọọya ti wọn jẹ, emi tiẹ ro pe boya Lọọya Falọla ran ẹnikan si mi ni, tori mi o reti pe Lọọya Salami fẹẹ wa mi wa… Emi naa o ki i ṣe ọmọ kekere nao, ọdun yii ni ma a pe fifti yias (50 years). October ta a fẹẹ mu yii ni ma a pe aadọta ọdun, ṣe ọmọde waa ni mi ni. Mo le ni bọdi kekere, mi o ki i ṣe eeyan kekere rara, ibi to ka mi mọ ni o, ọkunrin ni mi ti ko ba s’ọkunrin nile, bẹẹ ni, ọkunrin gidi ni mi, ọkunrin kan ṣoṣo bii wan miliọnu ni mi, mo f’Ọlọrun to lẹmii mi bura. Mi o ki i bẹru eeyan kankan. Mo le maa ṣe bii dindinrin fun-unyan, ṣugbọn ti mo ba yari… Nigba ti mo fariga mọ wọn lọwọ nibi pe ninu ki wọn pa mi, ki wọn yin gbogbo ibọn ọwọ wọn fun mi, tabi ki wọn paarọ ẹwọn ti mo wa, kia ni wọn paarọ ibi ti wọn fi mi si, tori mo yari gidi ni. Ti mo ba ti sun kan ogiri lẹyin ti mo ti kọkọ ṣe bii omugọ fun ẹnikan, ti mo ba yari, agbara wọn o le ka mi mọ.
Gbogbo gbigbe ti wọn gbe mi sọ sẹwọn yii, ko nitumọ si mi, tori mo gba pe o ti wa lakọọlẹ aye mi ni. Gẹgẹ bii ọrọ Baba mi, Ajani Bello, gbogbo ọrọ nipa agbara oogun, fiimu lasan ni, irin teeyan maa rin laye ẹ ti wa lakọọlẹ.
Ti mo ba jokoo nigba mi-in, ti mo ba ranti ọrọ tabi waasi Baba Bello, ara mi aa balẹ ni. Lọjọ ti Baba n ba mi ṣile, ti gbogbo awọn eeyan nla nla wa nikalẹ, awọn gomina awọn sẹnetọ, Gomina Oyinlọla, Gomina Mimiko, Sẹnetọ Omiṣore, bẹẹ bẹẹ lọ, gbogbo wọn ni wọn wa nikalẹ lọjọ naa, ibẹ ni Baba ti ni ‘gbogbo yin ti ẹ tẹle Sunday Igboho wa yii, tori ẹ n ri i lo ni, ẹ si mọ pe o lagbara, oogun wa lọwọ ẹ. Ṣugbọn agbara to ni, njẹ ẹ mọ ibi to wa. Ẹ o mọ ọn. Ọlọrun ti fi agbara si ara ẹ ni, ki i ṣe agbara tẹyin n wo yẹn, inu ara ẹ lagbara ẹ wa, iya to bi i lo jokoo yii, ki i ṣe Ajẹ.’
Tori ẹ, mo ti gba f’Ọlọrun nibi ti mo wa yii, mi o bẹru ẹnikan mọ. Tile-ẹjọ ba bẹrẹ pada, ma a sọ fun adajọ yẹn, ko si nnkan kan ti mo bẹru o, ti wọn ba fẹẹ da mi pada si Naijiria, o ti ya, ẹru o ba mi. Naijiria ti wọn n gbe mi lọ, afi ti ko ba si Ọlọrun nibẹ lo ku. T’Ọlọrun ba ti nbẹ nibẹ, ko si nnkan kan. Ṣebi Nnamdi Kanu lo wa lahaamọ ti wọn fi i si yẹn, ṣebi ohun temi n ja fun yii loun naa n ja fun.
Ẹni tẹ ẹ lọ sile ẹ loru, ṣe ẹ ti ke si i tẹlẹ to loun o wa ni. Ẹ waa lọọ ka a mọ’le loru, ẹ bẹrẹ si i yinbọn, armoured tank ni wọn fi fọ fẹnsi ti wọn wọle loru yẹn. Ki lo de? Mi o paayan, mi o jale, mi o ṣe nnkan kan nao. Latari pe mo sọ pe iya ti Naijiria fi n jẹ Yoruba ti to, a o ṣe mọ. Ohun ti mo sọ niyẹn, pe Fulani n pa wa nipakupa, ẹ wo bi wọn ṣe lọọ pa awọn eeyan wa n’Igangan lọjọsi, ti wọn n reepu wa, ti wọn n s’oriṣiiriṣii. Ṣebi mo wọ inu igbo funra mi, ti mo lọọ n le wọn funra mi ni. Ẹ o dẹ le ri ẹri kan pe mo paayan, mi o pa ẹnikan. Gbogbo ipolongo ti mo n ṣe, mi o gbe’bọn dani, mi o ṣe ẹnikẹni leṣe. Ohun ti mo n sọ ni pe awa la l’epo, awa la ni ọpọ nnkan, ṣugbọn wọn o jẹ ka j’ọrọ ẹ, wọn n fi iya jẹ wa ju.
Gbogbo Naijiria ti daru, eeyan o le rin l’alẹ mọ nisinyii. Ẹ o le gbera pe ẹ n lọ ibi kan ni Naijiria lalẹ mọ, Fulani maa ja’na, wọn maa jiiyan gbe ni, wọn le ni kawọn mọlẹbi lọọ mu tiri ọndirẹdi miliọnu (N300m) wa, iru igbesi aye wo la waa n gbe ni Naijiria yẹn.
Ohun ti mo n ba wọn fa niyẹn. Iyẹn ko i ti i pọ ju, ko to ohun ti wọn maa tori ẹ ni pe ki wọn lọọ pa mi. Mo si ti sọ fun wọn nibi pe to ba jẹ Naijiria ni wọn ni wọn fẹẹ gbe mi lọ, ki wọn maa gbe mi lọ, afi ti ko ba si Ọlọrun nibẹ lo ku.
Gbogbo asiko ti mo fi wa lahaamọ yii, o ye Ọlọrun. Ẹ jẹ ki n sododo fun yin o, agbara ijọba Bẹnẹ kọ lo mu mi silẹ o, o wu Ọlọrun Ọba bẹẹ ni o. Igbagbọ mi s’Ọlọrun ni pe oun lo mu mi wa sibi, oun naa ni yoo si yọ mi kuro nibi. Koda bi gbogbo lọọya to n ṣiṣẹ lori mi ba jawọ, mo fi titobi Ọlọrun bura, O maa mu mi kuro nibi. Ko si nnkan kan, mi o si bẹru nnkan kan mọ. Koda mo ti sọ fun wọn pe to ba ṣe Naijiria naa ni, ki wọn maa gbe mi lọ, ko si nnkan kan ti yoo ṣẹlẹ. Ọlọrun lo mọ atiwaye mi, atiwaye mi ko si lọwọ ẹnikankan. Baba mi loogun bii Ṣanpọnna, o loogun gidi, ti gbogbo eeyan si mọ bẹẹ, ṣugbọn o ti ku, iku pa a. Gbogbo irinajo aye mi, bi mo ṣe maa rin in, Ọlọrun ti kọ ọ sori mi, bi mo ṣe maa rin in, Ọlọrun ti mọ ọn. Talaka ni iya mi, iran wa o lowo. Ti wọn ba sọ fun baba mi lọjọ ti wọn bi mi pe ‘ọmọ tẹẹ bi yii, o maa lokiki o, o maa lowo lọwọ, gbogbo aye yoo si mọ ọn,’ baba mi aa jiyan ni pe ọna wo ni mo fẹẹ gbe e gba, ṣe pẹlu ile ahoro ti a n gbe.
Ṣe awọn lọọya yii waa ni Ọlọrun ni? Awọn lọọya ti wọn o le sọ f’adajọ pe wọn o gbọdọ gbe mi wa sibi, bi gbogbo wọn ṣe pọ to, ti lọọya n lọ bii mẹwaa, gbogbo wọn ni wọn gb’owo ribiribi, ẹni to gba tiri miliọnu, (3 million Naira) oni-tuu miliọnu n bẹ nibẹ, faifu miliọnu (5 million Naira), bi gbogbo wọn ṣe gba a lọọ niyẹn, sibẹ niṣeju wọn l’adajọ fi n gbe mi wa sẹwọn. Awọn lọọya to jẹ niṣeju ni wọn ni adajọ fi n de hankọọfu mọ mi lọwọ fun odidi ọjọ meje, ti wọn o le tu u, afigba ti Lọọya Falọla to o de, ṣẹ ẹ ri nnkan, ṣe awọn lọọya niyẹn, ki i si ṣe owo kekere lẹẹ gba, sibẹ, ẹ o le tu hankọọfu kuro lọwọ mi, lai ṣe pe mo jale, mi o rọọbu, mi o ṣe nnkan kan. Mi o bẹru lọọya kankan, mi o bẹru ẹnikan, gbogbo ara ti wọn ba fẹẹ fi mi da, mo ti wa pẹlu wọn, mo ti wa nibi.
Adekunle Arẹmu: Lọọya yẹn ni awọn infọmeṣọn kan loun fẹẹ waa fun yin loun fi wa…
Sunday Igboho: Mio fẹ, mi o niidi (need) ẹ. Infọmeṣọn Ọlọrun ni mo fẹ bi mo ṣe wa yii, mi o fẹ infọmeṣan ẹnikan. Mo ti sọ fun wọn bẹẹ tẹlẹ. Infọmeṣan ti wọn o ni, ki wọn fi gbe mi jade nibi ti mo wa yii, ki wọn ma fun mi, infọmeṣan Ọlọrun Ọba to ni mi nikan ni mo fẹ lọwọ ti mo wa yii.