Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n sọ pe boya iku ojiji to pa ọkunrin yii lasiko to n hu oku olokuu niboji, n’Ibẹrẹkodo, l’Abẹokuta, yoo kọ awọn yooku rẹ to n ṣiṣẹ ibi ọhun lọgbọn.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niṣẹlẹ yii waye niboji oku ti wọn maa n sin awọn Musulumi si, n’Ibẹrẹkodo, niluu Abẹokuta. Ọwọ oru lọkunrin ti ko sẹni to mọ orukọ rẹ naa ji lọ si saaree oku ọhun, o si ko awọn irinṣẹ ti yoo fi hu oku dani.
Ṣugbọn nibi to ti n hu oku naa lọwọ ni wọn ni o ti ṣubu sinu saaree ọhun, bẹẹ ni ko le tẹsiwaju ninu iṣẹ to n ṣe naa mọ.
Ẹjẹ tilẹ bẹrẹ si i jade lẹnu rẹ bi wọn ṣe wi, nigba tawọn alaboojuto si debẹ ni wọn ri i pe ẹni to waa hu oku olokuu ti ba oku nile, oun funra rẹ si ti dẹni to n ba ara ọrun ṣe.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Imaamu agba Oke-Ọna, Alaaji Musiliu Nasir, ṣalaye pe kutu hai lawọn kan waa sọ foun pe ẹni kan waa hu oku nitẹ oku awọn Musulumi, n’Ibẹrẹkodo. Boya ori lo fẹẹ ge, boya gbogbo ara oku naa lo si fẹẹ di sapo ni, wọn ṣaa ni nibi to ti n ṣe e lọwọ lo ti ṣubu sinu saaree naa, o si ti ku patapata.
Ọkunrin kan bayii to ni oun ko fẹẹ darukọ oun, ṣalaye fun ALAROYE pe itosi iboji naa ni ile oun wa, oun si maa n ri ohun to n ṣẹlẹ nibẹ daadaa.
O ni ni nnkan bii aago meji aabọ oru ọjọ Sannde yii, oun kofiri ẹnikan niboji naa, ara si fu oun nigba toun ri i bo ṣe n ṣe. O ni ṣugbọn ẹru n ba oun, oun ko le jade loru naa. Afi bi ilẹ ṣe mọ tawọn ba oku ọkunrin kan to ki ori bọ saaree to n hu lọwọ, bẹẹ lawọn nnkan to fi n hu ori oku naa si wa lẹgbẹẹ rẹ nibẹ.
Awọn ọlọpaa ni wọn waa gbe oku naa lọ bi wọn ṣe wi. Awọn irinṣẹ ti wọn si ni wọn ba lẹgbẹẹ ọkunrin naa ni ada, ọbẹ kan ti wọn lo mu gidi ati foonu rẹ to wa lapo rẹ nigba to ku iku ojiji naa.