L’Ọjọruu ọsẹ yii ni esuke wọ rara ni kootu giga ilu Abuja, nibi ti wọn ti n ṣe ẹjọ Sunday Igboho. Lọọya awọn DSS, Idowu Awo, sọ fun ile-ẹjọ pe awọn adigunjale da ẹlẹgbẹ oun to n gbe faili ẹjọ awọn ọmọ ẹyin Igboho lọna, wọn si gba a lọwọ rẹ.
Ọkunrin naa tẹsiwaju pe mọto awọn ọdaran ti wọn maa n ti ẹni to ba ko si wọn lọwọ bọ silẹ lori ere, eyi ti wọn n pe ni wan ṣansi (one chance) ni ẹlẹgbẹ oun naa wọ lai mọ, bi wọn ṣe gba faili ẹjọ naa lọwọ rẹ niyẹn.
Lọọya awọn DSS yii tẹsiwaju pe ki i ṣe iwe ẹjọ yii nikan ni wọn gba lọwọ rẹ, o ni wọn tun gba awọn nnkan mi-in to tun ni lọwọ naa.
Ṣugbọn lọọya awọn ọmọ ẹyin Igboho, Pẹlumi Ọlajẹngbesi, sọ pe kayeefi nla gbaa ni ohun ti agbẹnusọ awọn DSS sọ yii.
O ni bi ole ba le da DSS lọna l’Abuja bi wọn ṣe lagbara to, ti wọn ni ẹṣọ alaabo lawọn to, a jẹ pe ko si ireti kankan mọ fun mẹkunnu lasan niyẹn.
Lọọya DSS to ni iwe ipẹjọ ti sọnu yii ko yee sọ tiẹ ṣa, niṣe lo ni ki Adajọ Obiora Egwuatu to n gbọ ẹjọ naa fun awọn lọjọ mi-in ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.