Faith Adebọla
Isọrọ nigbesi, isunmu-si nigbete-jo, ọrọ yii lo ṣe rẹgi pẹlu bi isọrọ-sira-ẹni ati oko-ọrọ ṣe n waye lasiko yii laarin Agbenusọ ileeṣẹ Aarẹ, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, ati ilu-mọ-ọn-ka aṣaaju ẹsin Musulumi l’Oke-Ọya nni, Sheikh Ahmed Abubakar Gumi.
Ṣe wọn ni ẹni to sọko sori orule lo fẹẹ gbọ ohun onile, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, oludamọran pataki fun Aarẹ, lo kọkọ sọrọ ninu apilẹkọ kan to fi lede l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, lati fi erongba rẹ han lori ọna tuntun tawọn ọmoogun ilẹ wa n gba koju awọn janduku afẹmiṣofo ti wọn n han awọn araalu leemọ, paapaa l’Oke-Ọya. Fẹmi ni bawọn ologun ṣe n rọjo ọta ibọn ṣọọrọṣọ sibudo awọn eeyan keeyan yii daa bẹẹ, ohun tijọba ti n reti ki wọn ṣe ni, inu awọn araalu si dun si i.
O ni inu oun dun pe bawọn ọmoogun ofurufu ṣe n ju ‘akara’ gbigbona lu wọn latoke, ti wọn n ku bẹẹrẹbẹ, niṣe lawọn to ṣẹku ninu wọn n fara kona ọta ibọn to n rọjo lọwọ awọn ọmọ ogun ori ilẹ, tori niṣe lawọn ọmoogun fẹẹ gba awọn igbo tawọn janduku fi ṣe ibuba mọ fee-fee-fe lọtẹ yii.
Ṣugbọn Fẹmi ko fi mọ sibẹ, o ni iyalẹnu lo jẹ foun pe ẹnikan le wa nibi kan ti yoo maa sọrọ to le bomi tutu sọkan awọn ọmoogun ilẹ wa.
O ni: “Imulẹ awọn janduku agbebọn kan la fidi ẹ mulẹ pe o sọ pe bawọn ṣọja ṣe n gbogun ti awọn janduku yii ko le kẹsẹ jari, pe aṣedanu ni wọn n ṣe, ko le seso rere. Wọn lo tun sọ pe ko sibi kan tawọn janduku agbebọn n lọ, ko sohun to le ṣi wọn lọwọ iṣẹẹbi wọn. Ṣe ootọ ọrọ niyẹn ṣa? Irọ gbuu ni. Wọn maa kuro nilẹ yii, wọn o si ni i lọ sibi meji, ina ọrun apaadi nile wọn.”
Fẹmi ni ẹni ti ohun tijọba atawọn ologun n ṣe lasiko yii ko ba tẹ lọrun, o le lọọ darapọ mọ awọn janduku ni Zamfara, ko lọọ ba wọn jẹ Ṣawama, iyẹn ounjẹ eebo aladun kan, ṣugbọn o daju pe owe ni Fẹmi n pa, iku dẹdẹẹgbo lo pe ni Sawama yii, leyii to tumọ si pe tọhun yoo fiku ṣefa jẹ ni.
Bo tilẹ jẹ pe Fẹmi o darukọ ẹni to sọrọ to n fesi le lori naa, ko sẹni ti ko mọ pe Sheikh Abubakar Gumi lo n ba wi. Idi si ni pe Gumi lo ti kọkọ sọrọ ti Adeṣina fa yọ ninu apilẹkọ rẹ yii. Laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, to kọja ni Gumi ti sọrọ lori ikanni ayelujara rẹ pe ata akara ti ko ran ikọ ni igbesẹ akọlu tawọn ologun bẹrẹ si i ṣe lakọtun ta ko awọn janduku agbebọn ni Zamfara bayii, o ni awọn janduku naa lo le lọ sibi kan, ko sibi kan lagbaaye tijọba ti n fi awọn ologun koju awọn janduku ti wọn n ṣaṣeyọri, o loun kijọba pe wọn ku aṣedanu ati ifakoko-ṣofo.
Bi owe ba jọ tẹni, teeyan o ba dahun, wọn ni ẹru ija n ba onitọhun ni. Bi Gumi ṣe gbọ nipa oko ọrọ ti Fẹmi Adeṣina ju ba a ninu apilẹkọ yii, igbona-igbooru la a jẹ oku ọpọlọ lo fi ọrọ naa ṣe, aṣalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, kan naa ni Gumi gba ori atẹ fesibuuku rẹ lọ, lati fesi pada fun Fẹmi, esi ọhun ko si bara de rara.
Gumi sọ pe: “Iwọ “bọi-bọi” lasan-lasan yii n pe mi ni ọrẹ awọn janduku. Emi ki i ṣe ọrẹ awọn agbebọn o, olufẹ orileede mi ni mi, olufẹ agbegbe mi, olufẹ ipinlẹ mi, olufẹ awọn eeyan mi, ati afẹdaa-fẹre ni mi.”
Gumi waa ṣalaye pe bijọba ṣe yẹ ko fa awọn janduku loju mọra, to yẹ ki wọn ba wọn sọrọ, ki wọn si pese itọju to yẹ fun wọn, wọn o ṣe bẹẹ, idi si niyẹn ti wahala ijinigbe ati ipaniyan ko ṣe rọlẹ, ko si le rọlẹ afi tijọba ba ṣe ohun to yẹ.
O tun lawọn agbebọn ti mọ ọpọ ọna ẹburu ti atako awọn ologun ko fi le ran wọn, ati pe wọn o nigbọkanle ninu awọn ologun ati ijọba mọ, nitori lọpọ igba tawọn agbebọn naa ba lawọn ti sọrẹnda, ti wọn si ko nnkan ija wọn silẹ, niṣe ni wọn tun n ṣe wọn yankanyankan nigbẹyin.
Lopin ọrọ rẹ, Gumi tun pada sọdọ Fẹmi Adeṣina, o ni:
“Ṣe ẹ ri i, ni tawọn ti wọn elerokero to jẹ opo kan ṣoṣo nironu wọn gba lọ yii, ti ko si nnkan to nilaari ninu ọrọ ẹnu wọn, itukutu, eebu ati ọrọ ẹgan, a ti mọ wọn lanaa ko too di oni, bi awọn ṣe ri ni tiwọn niyẹn, b’Ọlọrun ṣe da wọn niyẹn. Ko si wahala rara o, eeyan o le reti ki igbọnsẹ mu oorun lọfinda jade, ọrọ buruku lo wa lẹnu ẹyẹ wọn.”