Faith Adebọla
Lẹyin ọjọ meji ti olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin apapọ, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila, lọọ ki Aṣiwaju Bọla Tinubu, gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri naa tun ti gbalejo awọn gomina tẹlẹ meji lati Oke-Ọya ilẹ wa.
Gomina ana fun ipinlẹ Sokoto, Aliyu Wamako ati ẹlẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Zamfara, Abdulaziz Yari, lo tẹkọ leti lọ si London, lorileede United Kingdom, nibi ti Tinubu ti n gbatẹgun alaafia ati itọju iṣegun lori ailera ara rẹ.
Ninu iroyin kan ti wọn fi lede lori abẹwo yii, wọn sọ pe awọn gomina naa ba Bọla Tinubu daadaa, wọn ni ara rẹ ti ya si i, o ba awọn sọrọ, awọn si jọọ jiroro nipa iṣejọba Naijiria, ipenija ti orileede yii n koju lori eto aabo, ati awọn ọrọ mi-in.
Lẹyin ijiroro wọn ni wọn jọ ya fọto kan, wọn nibi ti Tinubu ti duro lori ẹsẹ rẹ, laarin awọn alejo mejeeji naa.
Lati bii oṣu meji ni sẹyin ni baba naa ti lọọ tọju ara rẹ niluu oyinbo, ọgọọrọ awọn oloṣelu atawọn eeyan nla nla lawujọ si ni wọn n ṣabẹwo ikini sọdọ rẹ, bẹrẹ latori olori orileede wa, Aarẹ Muhammadu Buhari, Gomina ipinlẹ Ekiti, Ondo ati Eko, atawọn mi-in.