Faith Adebọla, Eko
Niṣe loju awọn obi ati mọlẹbi ọmọbinrin ẹni ọdun mejidinlogun kan, Oloogbe Monsurat Ojuade, ro korokoro, to si le roro fun omije nigba ti wọn n gbalejo Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, to ṣabẹwo ibanikẹdun si wọn latari iṣẹlẹ ọmọ wọn ti ọlọpaa kan, Sajẹnti Samuel Phillips, yinbọn pa nifọnna ifọnṣu lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii.
Nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Aje, Mọnde yii, ni kọmiṣanna ọlọpaa naa pẹlu ikọ rẹ lọọ fi ẹdun ọkan wọn, ati lẹta ibanikẹdun ti ọga agba patapata funleeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa, IG Alkali Baba Usman kọ, jiṣẹ fawọn mọlẹbi ọmọbinrin naa.
Odumosu ni ọkan oun gbọgbẹ lati gbọ nipa iṣẹlẹ yii, o si ka oun lara pe gbogbo igbiyanju lati doola ẹmi ọmọbinrin naa papa ja si omulẹmofo, tọmọ naa fi jade laye.
O ni Ọlọrun yoo bu ororo itura si ọkan wọn, Ọlọrun yoo si tẹ ọmọbinrin wọn si afẹfẹ rere.
Bakan naa lo fi da wọn loju pe ki i ṣe pe idajọ ododo maa waye lori ọrọ yii nikan ni, awọn o ni i jẹ ki idajọ naa falẹ rara, tori arikọgbọn leyi gbọdọ jẹ fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba, paapaa awọn agbofinro lati tubọ maa ṣọra ṣe lẹnu iṣẹ wọn.
O lawọn ti fi pampẹ ọba gbe Sajẹnti Phillips ti wọn lo da ọran yii, o si ti wa niwaju igbimọ to n wadii ọrọ naa, laipẹ lawọn maa gbe igbesẹ ibawi to kan lori ẹ, tiwadii ba ti pari.