Florence Babaṣọla
Adajọ ile-ẹjọ giga ilu Oṣogbo ti paṣẹ pe ki Oloye Kayọde Eṣuleke, ọmọ rẹ, Fashọla, atawọn eeyan meji mi-in lọ naju lọgba ẹwọn ilu Ileṣa titi di ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, ti igbẹjọ yoo tun waye lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn.
Eṣuleke lo ni eegun Ẹsubiyi ti awọn alatilẹyin rẹ atawọn ijọ Kamorudeen Central Mosque, kọju ija sira wọn lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun yii, lagboole Oluọdẹ Aranyin, niluu Oṣogbo, eyi to yọri si iku Imaamu Moshood Salaudeen.
Ẹsuleke, Fashọla, Kọla Adeọṣun ati Akeem Idowu ni wọn fara han ni kootu lori ẹsun mẹtala ọtọọtọ to ni i ṣe pẹlu ipaniyan, dida omi alaafia agbegbe ru, biba nnkan jẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nigba ti wọn ka awọn ẹsun naa si wọn leti, wọn sọ pe awọn ko jẹbi. Agbẹjọro fun awọn olujẹjọ, Abimbọla Ige, sọ fun Onidaajọ Ayọ Oyebiyi pe oun ti mu iwe wa siwaju ile-ẹjọ lori beeli awọn olujẹjọ.
Ige rọ kootu lati fun Eṣuleke ni beeli nitori ailera ara rẹ, o ni o ṣẹṣẹ ṣiṣẹ-abẹ kan laipẹ yii ni, eleyii to nilo ko maa lọ sileewosan loorekoore.
Bakan naa lo rawọ ẹbẹ si kootu lati fun awọn olujẹjọ mẹta to ku ni beeli nitori pe ọmọ bibi ilu Oṣogbo ni wọn, wọn si ṣetan lati fi awọn oniduuro to lorukọ silẹ, wọn ko si ni i sa lọ fun igbẹjọ.
Ṣugbọn agbẹjọro lati ileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Ọṣun, Biọdun Badiora, ta ko arọwa agbẹjọro olujẹjọ, o ni eto iwosan to peye wa fun Eṣuleke ni ọgba ẹwọn ti wọn ba gbe e lọ ati pe awijare Ige pe awọn to ku ko ni i sa fun igbẹjọ ko ṣee tẹle rara.
Onidaajọ Oyebiyi paṣẹ pe kawọn olujẹjọ mẹrẹẹrin maa lọ sọgba ẹwọn Ileṣa titi di ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹsan-an, ti ile-ẹjọ yoo sọrọ lori gbigba beeli wọn.