Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ ẹṣọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti sọ pe ajọ naa ti fi Adamu Sabi ati iya ẹ, Fati Sime, ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Bẹnẹ, ti wọn bara wọn laṣepọ titi ti wọn fi bimọ mẹta funra wọn ṣọwọ si ilẹ Olominira Bẹnẹ pada, lẹyin iwa ko tọ ti wọn hu ọhun.
Agbẹnusọ ajọ ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, lo fi iroyin naa lede niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara pe awọn ti fi iya ati ọmọ ti wọn n ba ara wọn laṣepọ titi ti wọn fi bimọ mẹta naa sọwọ si orile-ede Olominira Bẹnẹ, ti i ṣe ilu abinibi wọn lẹyin iwadii ti ajọ naa ṣe ti awọn si ri i pe wọn o ni iwe ọmọ igbeluu Naijiria, ọna aitọ ni wọn gba wọ ilẹ yii.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni agbẹnusọ ajọ naa, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afolabi, ba awọn oniroyin sọrọ ni ilu Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara, o salaye pe iya to bi Adamu ninu ti bi ọmọ mẹta fun un, ati pe olori ileto kan, Malam Bandele, niluu Mosher, nijọba ibilẹ Kaiama, nipinlẹ Kwara, lo mu ẹsun lọ si ọdọ ajọ ọhun pe ṣe ni ọkunrin naa mu iya rẹ gẹgẹ bii iyawo, to si n ba a laṣepọ, to tun n bimọ fun un, ti ajọ naa ti mu arakunrin ọhun ati iya, ti wọn si ti wa ni galagala ajọ naa, ṣugbọn ni bayii, wọn ti da iya ati ọmọ rẹ pada si ilẹ olominira Bẹni.