Nibi tawọn eleyii ti n ṣe fayawo epo ti wọn fẹẹ gbe kọja si ilẹ Benin lọwọ ti tẹ wọn

Faith Adebọla

Gende mẹrindinlogun lawọn afurasi ọdaran tọwọ awọn agbofinro tẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, l’Erekuṣu Abagbo ati Snake, nijọba ibilẹ Eti-Ọsa, nipinlẹ Eko, nibi ti wọn ti n ṣe fayawọ epo rọbi ti wọn fẹẹ gbe kọja sorileede Bẹnẹ lọwọ ti ba wọn.

Awọn ọmoogun ori omi ilẹ wa ti wọn n ṣiṣẹ ninu ọkọ oju-omi Beecroft, ni wọn lọọ fi pampẹ ofin gbe awọn afurasi naa, lẹyin ti olobo ti ta wọn ṣaaju pe iṣẹ fayawọ ni wọn n ṣe, epo rọbi ilẹ wa ni wọn n ji wa, ti wọn si n fi kẹẹgi rọ ọ lọọ ta lawọn ilu ẹyin odi.

Lọjọ tọwọ ba wọn yii, mọkanla ninu awọn ọbayejẹ ẹda yii ni wọn wa ninu ọkọ oju omi ayara-bii-aṣa fiber boat meji ti wọn n lo, wọn si ni kẹẹgi bii ọgọrin ti wọn rọ epo bẹntiroolu kun temutemu ni wọn fẹẹ gbe sọda lori omi, kawọn ọmoogun too gba fi ya wọn, ti wọn si le wọn ba.

Kọmanda awọn ọmoogun ọhun, Commodore Bashir Mohammed ninu atẹjade kan to tẹ ALAROYE lọwọ lori iṣẹlẹ ọhun sọ pe awọn marun-un mi-in tawọn mu lẹyin naa, agbegbe Snake Island lawọn ti mu wọn, inu ọkọ oju-omi lawọn naa wa pẹlu kẹẹgi epo bẹntiroolu mọkanla ti wọn n ṣe fayawọ rẹ.

O lawọn afurasi ọdaran naa jẹwọ pe awọn lawọn wa nidii bibẹ awọn ọpa epo ileeṣẹ NNPC kaakiri ipinlẹ Eko, paapaa lawọn agbegbe Badagry ati Ejigbo, ibẹ ni wọn ti n ri epo bẹntiroolu ti wọn n ṣe fayawọ rẹ.

Ba a ṣe gbọ, wọn ti taari awọn obilẹjẹ ẹda naa sileeṣẹ Sifu Difẹnsi, ibẹ niṣẹ iwadii to kan ti n tẹsiwaju, ti wọn yoo si gbe igbesẹ to ba ofin mu lori wọn.

Leave a Reply