Faith Adebọla, Eko
Olori ileegbimọ aṣoju-ṣofin ilẹ wa l’Abuja, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila, ti wọn lo sọ pe ko siyatọ laarin awọn to n ja fun yiya kuro lara Naijiria ati awọn eeṣin-o-kọku afẹmiṣofo, o lọmọ iya kan naa ni wọn, ti sọ pe oun ko sọ bẹẹ mọ, o ni wọn yi ọrọ oun po ni.
Ninu iroyin to n ja ranyin lori atẹ ayelujara tawọn eeyan ka mọ olori aṣofin naa lẹnu, wọn lo jade ninu ọrọ ikini-kaabọ to ba awọn ẹlẹgbẹ rẹ sọ nileegbimọ ọhun l’Ọjọruu, Wẹsidee yii lapa kan pe:
“Nibi ta a de yii, a ti gbajumọ eto aabo orileede wa lori erongba awọn eeṣin-o-kọ ‘ku afẹmiṣofo ti wọn fẹẹ yi aye pada si ijọba tiwọn atawọn janduku agbebọn ti wọn n ṣoro bii agbọn tori owo ti wọn n ri. Omi-in to yẹ ka fi kun un bayii ni tawọn kan ti wọn n halẹ, ti wọn si dunkooko mọ wa bii tawọn ta a sọ yii. Ni Guusu, Iwọ-Oorun ati Ila-Oorun Naijiria, awọn ọmọ isọta atawọn ọdaran ti wọn n ṣe bii pe ajijagbara fun pinpin Naijiria lawọn ti bẹrẹ si daluru gidi, wọn n da ẹmi eeyan legbodo, wọn si fẹẹ doju ọrọ-aje bolẹ, lodi si awa ọmọ Naijiria ẹlẹgbẹ wọn ati ijọba Naijiria pẹlu.
Awọn eeyan yii, to jẹ pe wọn o lero meji ju bi wọn ṣe maa huwa ika sọmọlakeji wọn, to jẹ gbogbo ọna ni wọn fi n wa bi wọn ṣe maa ba dukia ẹni ẹlẹni jẹ, ti wọn maa da eto ẹkọ, okoowo, ati tawọn ileeṣẹ ru, to jẹ gbogbo ọna ni wọn n ṣan lati ba awọn ileeṣẹ ijọba jẹ, ki wọn ba awujọ ati adugbo jẹ, to jẹ pe wọn ki i fẹ ba ijọba fikun lukun, bẹẹ ni wọn o fẹẹ gbọ ero mi-in to yatọ si tiwọn nikan, wọn o yatọ si awọn Boko Haram ati awọn ISWAP. Ta a ba fun wọn laaye diẹ si i, wọn maa na orileede wa tan bii owo ni, wọn si maa pa a run.”
Bayii ni Fẹmi sọrọ rẹ, ṣugbọn bi ọrọ naa ṣe bọ sori atẹ ayelujara, lawọn eeyan ti n sọko ọrọ loriṣiiriṣii, wọn lọrọ ti ko yẹ ko tẹnu ọmọ Yoruba atata tabi olori jade lọrọ ọhun. Bawọn kan ṣe n bu u lawọn mi-in n sọ pe sọ agbara lo n pa a bii ọti to fi n tutukutu.
Eti ọkunrin naa ko di si bawọn eeyan ṣe n sọrọ si i, boya eyi lo mu ko lọọ kọ atẹjade mi-in, leyii to fi sọ pe wọn ti n yi ọrọ toun sọ ọhun po, o ni wọn ti n fun un ni itumọ mi-in.
Oludamọran si Abẹnugan awọn aṣofin naa lori eto iroyin, Ọgbẹni Lanre Lasisi, sọ pe ọga oun ko darukọ awọn to n ja fun Yoruba Nation tabi Biafra o, bẹẹ ni ki i ṣe awọn lo n ba wi rara.
O ni awọn janduku ati onijangbọn ẹda to wa lawujọ wa ti wọn n wa nnkan ti wọn maa fi boju lati ṣọṣẹ tabi da rugudu silẹ ni Gbajabiamila n bawi.
Sibẹ titi di ba a ṣe n sọ yii lawọn eeyan ta ku, wọn ni irọ gbuu ni Fẹmi n pa, wọn ni lẹyin to sọrọ tan lo ṣẹṣẹ n ro abajade rẹ, eyi lo mu ko sọ p’oun o sọ bẹẹ mọ, wọn loju lagba n ya, agba ki i ya’nu.