Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Alaga The Osun Progressives (TOP), to wa ninu ẹgbẹ oṣelu APC l’Ọṣun, Rẹfrẹndi Adelọwọ Adebiyi, ti sọ pe irọ patapata ni ahesọ kan to n lọ kaakiri pe ipade alaafia ti n waye laarin wọn ati Gomina Gboyega Oyetọla.
Adebiyi ṣalaye fun ALAROYE pe ṣe ni awọn alatilẹyin Oyetọla ti wọn pe ara wọn ni Ileri Oluwa n lo ahesọ naa lati tan awọn araalu jẹ, ki wọn le maa foju alaidaa wo awọn TOP.
O ni ero wọn ni lati lo ahesọ naa lati fi ko awọn TOP ni papamọra, ki wọn le tẹ ifẹ ọkan wọn lọrun nitori gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ APC l’Ọṣun bayii lo n fi han pe awọn IleriOluwa atawọn alatilẹyin rẹ ko ni ẹmi alaafia rara.
Adebiyi fi kun ọrọ rẹ pe bawo ni awọn ti wọn n pariwo alaafia yoo ṣe maa yọ awọn ọmọ ẹgbẹ lẹnu, ti wọn yoo maa fojoojumọ ṣejamba fun ẹnikẹni to ba ti le sọ pe TOP loun wa.
O ni bawo leeyan a ṣe mu paṣan lọwọ ọtun, ti yoo gbe ẹkọ sọwọ osi, ti yoo si maa reti ki ewurẹ wa sọdọ oun waa jẹun? O sọ pe alaafia ko le si nibi ti wọn ba ti n ṣekọlu si awọn ti wọn ba fura pe wọn koriira awọn.
Ọkunrin to ti figba kan jẹ alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun ọhun sọ siwaju pe awọn ko le gbagbe bi ọkan lara awọn kọmiṣanna Oyetọla ṣe ran awọn tọọgi sipade awọn TOP niluu Ileefẹ laipẹ yii.
Bakan naa lo mu un wa si iranti bi awọn janduku kan ṣe kọ lu awọn TOP ni sẹkiteriati ẹgbẹ wọn lagbegbe Ogo Oluwa, niluu Oṣogbo, lọjọ kẹrinla, oṣu kẹjọ, ọdun yii, lasiko ti wọn ko iwe ẹsun lọ sibẹ lori idibo wọọdu to waye.
“Ko si igbesẹ alaafia kankan ti wọn fẹẹ gbe nitori ihuwasi gomina ati alaga ẹgbẹ APC l’Ọṣun ko jọ ti olufẹ alaafia, awọn mejeeji ko fẹ iyipada rere ninu ẹgbẹ, idi si niyẹn ti wọn ko ṣe figba kankan jade sita lati sọrọ nipa bi awọn tọọgi ṣe n lu awa TOP lalubami kaakiri ilu.
“Mo fẹẹ fi da yin loju pe gbogbo igbesẹ alaafia to ba wa lati ọkan to tẹriba la ṣetan lati fi ọwọ sowọ pọ pẹlu, ṣugbọn ki awọn Ileri Oluwa mọ pe awọn ko le ko wa laya jẹ rara.
“Bakan naa ni mo ke si alaga apapọ igbimọ alaamojuto ẹgbẹ wa lati mọ pe ina wa lori orule ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun, bẹẹ la pe awọn agbofinro lati tubọ ṣan ṣokoto wọn lori aabo ẹmi ati dukia awọn araalu.”