Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Nnamdi Omeka lọmọkunrin to ko ọta ibọn lọwọ yii n jẹ, ọmọ ọdun mọkanlelogun (21) ni. Lọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an yii, lọwọ awọn ọlọpaa ba a lagbegbe Ile pupa Iloye, ni Sango-Ọta, nibi toun ati ikeji ẹ ti fẹẹ ja mọto gba lọwọ ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Rasak Hamed.
Ipe ‘ẹ gba wa’ ni DPO teṣan ọlọpaa Sango gba lọjọ naa, ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ku iṣẹju mẹẹẹdogun. Ẹni to pe naa ṣalaye pe ikọ ẹlẹni meji kan n ṣọṣẹ lọwọ lagbegbe ọhun, wọn ni nnkan ija lọwọ, wọn si fẹẹ gba mọto lọwọ ẹnikan.
Awọn ọlọpaa gba ibẹ lọ, wọn si ba ikọ ẹlẹni meji to n ṣọṣẹ lọwọ naa nibẹ. Gẹgẹ bi alaye Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, o ni bawọn adigunjale ti wọn ti n yinbọn kiri tẹlẹ lati dẹruba awọn eeyan ṣe kofiri awọn ọlọpaa ni wọn bẹrẹ si sa lọ, wọn ko duro mọ.
Awọn ọlọpaa naa bẹrẹ si i le wọn lọ, pẹlu iranlọwọ awọn eeyan to wa nitosi, ọwọ tẹ eyi to n jẹ Nnamdi Omeka yii, ẹni keji rẹ sa lọ ni tiẹ.
Ọta ibọn mẹrin ti wọn ko ti i yin lawọn ọlọpaa ba lọwọ Nnamdi, wọn si tun ri ọkan ti wọn ti yin lọwọ ẹ pẹlu.
CP Edward Awolọwọ Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn wa ikeji Nnamdi to sa lọ naa ri, ki wọn si gbe oun tọwọ tẹ lọ sẹka iwadii gidi.