Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti mu ẹlẹran maaluu kan, Nawali Bala, niluu Patigi, nijọba ibilẹ Patigi, nipinlẹ Kwara, fẹsun pe o n ta ẹran ti ko daa fun awọn eeyan.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, ni Agbẹnusọ ajọ naa ni Kwara, Ọgbẹni Babawale Afolabi, fọrọ naa lede niluu Ilọrin. O ni ni kete ti ọwọ tẹ afurasi ọhun, Bashiru Bala Zuru, to n ta ẹran to ti bajẹ, to si lewu fun alaafia awọn araalu lo jẹwọ pe ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Dantani Jayewu, to n gbe Okoloke, nipinlẹ Kogi, lo gbe ẹran naa foun ki oun maa ta a. Lẹyin ayẹwo ti wọn ṣe si ẹran naa finnifinni latọwọ ileeṣẹ to n ri si ọrọ ayika nipinlẹ Kwara ni wọn sọ pe o le ṣe akoba fun alaafia araalu.
Ọga agba ajọ ọhun, Ọgbẹni Makinde, ti waa sọ pe awọn yoo foju afurasi naa ba ile-ẹjọ lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii.