Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ogun gidi ni Oluwoo ti ilẹ Iwo, Ọba Abdulrọsheed Adewale Akanbi, gbe ti awọn oriṣa ilẹ Yoruba bayii, o ni awọn ni wọn n ko ba iran Yoruba, ko si le daa fun wọn nitori ti awọn oriṣa naa ti ta.
Koda, Oluwoo fi kun alaye ẹ pe ko si bi agbara iṣejọba Naijiria yoo ṣe bọ sọwọ iran Yoruba, nigba to jẹ iboriṣa ti wọn n ṣe nibi ti pọ ju.
Oluwoo sọ pe awọn Hausa naa ni yoo maa dari Naijiria yii lọ, nitori awọn ki i bọ oriṣa, Ọlọrun to ju oriṣa lọ ni wọn n gbọrọ si lẹnu, idi niyẹn ti aṣẹ yoo fi maa wa lẹnu wọn nibẹ, ti awọn ti wọn n bọriṣa yoo si maa ṣe ẹru wọn lọ.
Awọn oniṣọọṣi kan ni wọn n ṣe isọji, eyi ti wọn pe ni Iwo Crusade Total Deliverance, l’Ọṣun. Awọn eeyan naa ni wọn pe Ọba Adewale sibẹ gẹgẹ bii alejo, nibẹ ni Kabiyesi si ti bẹrẹ si i ṣe iwasuu lori ibọriṣa, to fi Saamu kẹrindinlogun, ẹsẹ kẹrin, gbe ọrọ rẹ lẹsẹ, to si rọ awọn pasitọ pe ki wọn gbogun ti ibọriṣa ni Naijiria.
Oluwoo sọ pe, “Ta ni Ṣango, Ọya, Ogun, Ọṣun atawọn to ku niwaju Ọlọrun. Gbogbo ẹyin tẹ ẹ ti jọba nilẹ Yoruba, mo fẹẹ kẹ ẹ mo pe ti ẹ ko ba fi oriṣa bibọ silẹ, ko ni i si alaafia fun yin.
“Ṣe ẹ ri gbogbo iṣoro ti gbogbo ẹyin eeyan n koju bayii, awọn ọba lo fa a. Gbogbo awọn oriṣa ti wọn ko saafin wọn ni, Bẹẹ, Ọlọrun lo ni agbara ati aṣẹ, ṣe ko waa ni i dija, kin ni atubọtan rẹ yoo jẹ
“Ko yẹ ki oriṣa wa laafin, ẹ lọọ sọ fawọn ọba. Iwọ gẹgẹ bii ọkunrin, o fẹyawo, iyawo yẹn waa mu ọkunrin mi-in wa sinu ile ẹ, bawo lo ṣe maa ri. Ohun tawọn ọba ilẹ Yoruba n ṣe lasiko yii niyẹn, bẹẹ wọn n wa ibukun Ọlọrun ọhun.
“Awọn oriṣa lo n daamu ilẹ Yoruba, k’agbara too le bọ si wa lọwọ, a gbọdọ dẹkun ibọriṣa. Nibo lagbara wa ni Naijiria lonii, ilẹ Hausa ni, nitori wọn ki i bọ oriṣa, Ọlọrun ni wọn fi n ṣe ipilẹ ijọba wọn.
“Ẹsin ajoji ni oriṣa bibọ nilẹ Yoruba. Ko ni i daa fawọn Oriṣa. Aye wọn ti ta. Ẹ yee lọ sojubọ”
Bẹẹ ni Oluwoo fibinu kede ni gbagede isọji naa, eyi ti fidio ẹ ti n jan ran-in lori ayelujara.
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo koro oju sohun ti Oluwoo wi yii, wọn ni kin ni oriṣa ni i ṣe pẹlu iṣejọba tabi pe ẹya kan ni yoo maa ṣejọba lọ.
Awọn mi-in sọ pe bii igba teeyan n ta ara ile ẹ lọpọ ni ohun ti ọba yii n wi, wọn ni ifẹ inu rẹ lo fi n sọrọ, ko si ro atubọtan tiẹ gan-an.
Ọkan lara awọn eeyan to koro oju sohun ti Oluwoo wi ni Araba Ifayẹmi Ẹlẹbuubọn. Baba naa sọ pe ko yẹ ki Oluwoo jọba nilẹ Yoruba, o ni ilẹ Araabu to fara mọ iṣe wọn lo yẹ ko ti jọba.
Ẹlẹbuubọn ṣalaye pe yoo dara fun Oluwoo ko lọọ jọba rẹ lọhun-un, ju ko maa bu awọn ọba Yoruba, ko si maa ba ẹṣin ti wọn ti n ṣe lọọdun gbọọrọ sẹyin jẹ lọ.