Faith Adebọla
Awọn agbaagba apa Oke-Ọya ilẹ wa ti sọ pe o ti foju han pe ijọba to wa lode yii ko loye ọrọ atunto to yẹ ki wọn ṣe si eto iṣejọba, iṣuna owo ati iṣelu ilẹ wa, wọn lawọn maa fa ẹni ti yoo le ṣeto atunto kalẹ lọdun 2023.
Bakan naa ni wọn sọ pe owo ti wọn n pa wọle labẹnu ni agbegbe Oke-Ọya to lati na fun agbegbe naa, ko pọn dandan kawọn gba lara owo-ori ọja ti wọn n pe ni VAT, eyi to da awuyewuye silẹ lasiko yii.
Alukoro ẹgbẹ awọn agbaagba ọhun, Norther Elders Forum (NEF), Dokita Hakeem Baba-Ahmed ni wọn fiṣẹ yii ran, oun lo sọrọ naa lasiko to n sọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo ori tẹlifiṣan ileeṣẹ Arise, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Ṣe ṣaaju ni awuyewuye ti n lọ lori igbesẹ tawọn ipinlẹ kan n gbe lati yọwọ kilanko ijọba apapọ ninu gbigba owo-ori ọja (VAT) lawọn ipinlẹ wọn, ọrọ ọhun to bẹrẹ lati ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Rivers si ti wa nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun to paṣẹ pe kijọba apapa, ajọ agboowo-ori wọn, FIRS, ati awọn ipinlẹ tọrọ kan si dawọ duro na titi tawọn yoo fi tun ẹjọ naa gbọ, ati ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa l’Abuja, bẹẹ si lawọn gomina mẹtadinlogun iha Guusu ti sọ lọsẹ to kọja pe ki awọn ijọba ipinlẹ maa gbowo naa lawọn fara mọ ni tawọn.
Lori ọrọ yii ni Baba-Ahmed n sọrọ le lori to fi ni “ẹ jẹ ka maa wo ohun tawọn ile-ẹjọ maa sọ. Awuyewuye tọrọ yii ti da silẹ paapaa fihan pe o ṣe pataki gidi ka lọọ tun ajọṣe to wa laarin iṣakoko awọn ijọba ilẹ wa wo, o yẹ ka foju ṣunnunkun wo o gidi ni.
Awa fara mọ atunto, latilẹ la ti n sọ pe kileegbimọ aṣofin apapọ tabi awọn ẹgbẹ tọrọ yii kan gbe igbesẹ lati tun nnkan to lorileede yii. Ti iyẹn o ba ṣee ṣe lasiko yii, a maa wa olori to maa le ṣe e fun wa lọdun 2023, tori ko jọ pe ọrọ atunto ta a n sọ yii ye ijọba Buhari rara. O yẹ ka wo bowo ṣe n wọle ati ba a ṣe n pin in.
Agbegbe Oke-Ọya ki i ṣe ilẹ akuṣẹẹ rara, a lowo, a lọrọ, ohun ta a ni to wa i jẹ, koda lai si awọn owo biliọnu tawọn ipinlẹ kan n pa lọdọ wọn. Ailowo lọwọ wa ko to nnkan ta a maa sọ d’ẹjọ lorileede yii.”
Ọkunrin naa tun ṣalaye pe awuyewuye lori ọrọ owo-ori ọja yii yẹ ko sin awọn onṣelu lapa Oke-Ọya ni gbẹrẹn ipakọ pe ki wọn ji giri lati ro awọn eeyan wọn lagbara si i. O ni ko si anfaani ninu bi eeyan ṣe pọ nilẹ Hausa ṣugbọn ti ọpọ wọn ko rọwọ họri rara. O lo yẹ kawọn gomina naa ti maa ronu ohun ti wọn maa ṣe tile-ẹjọ ba fi gbe sẹyin ipinlẹ Rivers ati Eko lori ọrọ VAT yii.
O ni ọpọ nnkan amuṣọrọ lo wa lagbegbe awọn to yẹ ki wọn ṣiṣẹ le lori. ‘‘Ti a ba ti yanju iṣoro aabo to mẹhẹ yii, pẹlu iranwọ ijọba apapọ, ẹ jẹ ka lọọ bẹrẹ si i palẹ oko mọ, kawọn agbebọn ma raaye sa si mọ, ka pada soko wa. Iṣẹ amuṣọrọ gidi ni iṣẹ agbẹ, a nilẹ, a lomi, a ni nnkan ọsin, a si lawọn nnkan amuṣọrọ abẹlẹ ta a le maa wa kusa rẹ. Kawọn gomina waa yee kawọ pọnyin reti owo mọnbe tijọba n fun wọn loṣoosu, ko boju mu rara.”