‘Ko sowo osu fawọn ọlọpaa agbegbe o’ 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka tipinlẹ Kwara, SP Ajayi Ọkasanmi, ti kede pe ko si owo-oṣu kankan fawọn ọlọpaa agbegbe nipinlẹ Kwara, tori pe wọn n ṣe e lọfẹẹ lati daabo bo agbegbe wọn ni.

Tẹ o ba gbagbe, ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ wa sọrọ naa nigba to ṣe abẹwo si ipinlẹ Kwara pe ileeṣẹ ọlọpaa ko sanwo fun awọn ọlọpaa agbegbe tori pe ki i ṣe isẹ ti wọn yoo maa ṣe gbowo, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa le maa fun wọn ni owo ‘gba, ma binu’

Ọkasanmi sọ fun gbogbo awọn ọlọpaa agbegbe nipinlẹ Kwara nibi ifọrọwerọ kan to ṣe lori eto ori redio kan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, pe ki wọn  ma ni i lọkan pe wọn yoo maa gba owo-osu, amọ ki wọn mọ pe wọn fẹẹ maa ṣiṣẹ sin agbegbe wọn ki aabo to nipọn le wa fun ẹmi ati dukia wọn ni, ṣugbọn igbakuugba ti owo ‘gba, ma binu’ ba yọ, yoo maa tẹwọn lọwọ.

Leave a Reply