Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Kọmiṣanna to n ri si idagbasoke awọn ọdọ nipinlẹ Kwara, Arabinrin Harriet Adenike Afolabi-Oshatimehin, ti n kọminu pẹlu bi awọn ọdọ ipinlẹ naa ṣe mu ṣiṣe ‘Yahoo’ gẹgẹ bii iṣẹ kan gboogi ti wọn yoo fi tete goke ọla, o waa rọ wọn pe ki wọn takete si irufẹ ero bẹẹ tori pe oko iparun ni.
Kọmisanna ọhun gba awọn ọdọ naa nimọran lasiko to n gbalejo awọn asoju ẹgbẹ akẹkọọ lorileede yii, (National Association of Nigerian Students NANS), ẹka tipinlẹ Kwara, eyi ti Aarẹ wọn, Salman Yusuf Isa, ko sodi lọ si ọfiisi rẹ. Nigba to n ba wọn sọrọ, o ni erongba ileeṣẹ to n ri si idagbasoke awọn ọdọ ni ki wọn sawari awọn ọdọ to ṣee mu yangan lawujọ nipa lilo igbesi aye wọn lati maa fi ṣe ohun to ni itumọ, ki wọn si jinna si awọn iwa ọdaran ti i ba ọjọ ọla ẹni jẹ. Afolabi-Oshatimehin waa fi aidunu rẹ han lori bi lilu jibi lori ẹrọ ayelujara ṣe jẹ ohun amuyangan laarin awọn ọdọ lawujọ bayii, ti ileeṣẹ naa si ti gbe eto kalẹ lati maa ṣe ilanilọyẹ fun awọn ọdọ nigba de igba, ki wọn le yi ọkan wọn pada kuro nibi iwa ọdaran ọhun ati ewu to wa nibi jibiti ori ẹrọ ayelujara.
O tẹsiwaju pe inu oun dun pe funra ẹgbẹ akẹkọọ naa ni wọn wa si ọfiisi oun, ti wọn si tẹpẹpẹ awọn oniruuru iṣoro ti wọn n dojukọ ninu ẹgbẹ ati ọna abayọ si awọn iṣoro naa, o waa rọ wọn ki wọn jawọ laapọn ti ko yọ nipa titakete si iwa lilu jibiti lori ẹrọ ayelujara ati iwa ọdaran mi-in to fara pẹ ẹ, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati gbogun ti iwa aitọ ọhun.