‘Awọn EFCC mẹẹẹdọgbọn fo fẹnsi wọle mi laarin oru, wọn lawọn ro pe ọmọ ‘Yahoo’ ni mi’

Faith Adebọla, Eko

Ori lo ko obinrin oniroyin kan, Abilekọ Nora Okafor, yọ lọwọ iku ojiji latari bawọn ẹṣọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu  mọkumọku nilẹ wa nni, EFCC, ṣe ya bo ile rẹ lọganjọ oru, awọn ọkunrin firigbọn bii mẹẹẹdọgbọn, wọn da jinnijinni bo awọn olugbe ile naa, wọn ba awọn dukia wọn jẹ, lẹyin eyi ni wọn waa sọ pe awọn ṣi ile ya ni, awọn ọmọ ‘Yahoo’ lawọn n wa kiri.

Okafor royin pe:

“Aago meji ku iṣẹju mẹrinlelogun geere ni aburo mi ji mi pẹpẹ lori bẹẹdi ti mo sun si, o ni awọn adigunjale ti fẹẹ wọle wa o, wọn ti wa lẹnu geeti, ti wọn n wa ọna lati wọle. Ha, ẹru ba mi. Mo kọkọ ro o pe nitori geeti ati waya ori fẹnsi wa maa n ba ina ẹlẹntiriiki ṣiṣẹ, pe ko le ṣee ṣe fun wọn lati wọle. Aṣe irọ ni, aago meji oru ni mo ri ọkan lara wọn lori fẹnsi, o fi irinṣẹ kan ge okun ina to wa lara waya, lo ba fo wọle, ẹlomi-in tun tẹle e, lẹyin eyi ni wọn bẹrẹ si i fi aake nla kan ja geeti latẹyin ki awọn to ku wọn le wọle, bi wọn ṣe ya bo ile wa niyẹn.

Awọn bii mẹẹẹdọgbọn ni, gbogbo wọn lo da aṣọ dudu boju bii tawọn adigunjale, wọn dihamọra pẹlu ibọn lọwọ wọn, wọn tun ko aake, irin atawọn nnkan ija mi-in dani, ọkọ ọlọpọn meji ni wọn gbe wa, aṣọ dudu ni wọn si wọ.

Mi o ki i wọṣọ sun, tori naa, mo sare wọ aṣọ tọwọ mi ba. Mo ti n sọ fun ara mi pe ‘mo gbe, wọn maa fipa ba mi lo pọ lonii, wọn si maa ji mọto mi gbe lọ.’ Adigunjale ni gbogbo wa fọkan si pe wọn jẹ.

Mo fẹrẹ ma ti i wọṣọ tan ti wọn fi ja wọnu yara mi, ni wọn ba n paṣẹ bii ologun: ‘doju bolẹ, ẹ tan’na, dọbalẹ sibẹ yẹn, foonu ẹ da, kọkọrọ mọto ẹ n kọ, tibi nkọ, tọhun nkọ.’ Mo mu foonu mi fun wọn, mo gbe kọmputa agbeletan mi naa fun wọn, wọn ni ki n fi nọmba aṣiri (pasiwọọdu) mi si i, mo si ṣe bẹẹ pẹlu ojora. Bi wọn ṣe n tẹ oriṣiiriṣii lori foonu mi ati kọmputa mi lọwọ, mo gbọ ariwo bawọn kan lara wọn ṣe n da abọ ati awo ru ni kiṣinni (kitchen) mi, mo gbọ bi wọn ṣe n fọ awọn awo mi. Gbogbo yara mi ni wọn gbọn yẹbẹyẹbẹ, afi bii ẹni pe abẹrẹ ni wọn n wa. Wọn tun ṣe bakan naa si yara aburo mi, ko sibi ti wọn o fọwọ ba.

Nigba to ya, wọn ni ki n dide, ki n tẹle awọn lọ sisalẹ ile. Mo ri i pe wọn ti ko awọn alajọgbele mi naa de ibẹ, wọn ti lu aburo mi ọkunrin bii ẹni lu aṣọ ofi. Wọn gbiyanju lati ṣi awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti kaluku gbe sinu ọgba. Ẹnu ya mi nigba ti wọn ṣi aṣọ dudu ti wọn da bori, mo ri i pe ọlọpaa EFCC ni wọn, mo pariwo pe ‘kinla!’ ni ọga wọn ba paṣẹ pe ki n gbẹnu dakẹ. Wọn beere iṣẹ ti kaluku wa n ṣe, ẹmi ni akọroyin ni mi, aburo mi dahun pe dokita loun, ẹlomi-in ni ‘lọọya’ ati bẹẹ bẹẹ lọ, ni ọga wọn ba wo wa titi, o ni ‘a kan fakoko ṣofo wa sibi yii ni ṣa.’

Mo beere pe ki wọn sọ adirẹsi wọn fun wa ki n le waa gba foonu ati kọmputa mi to wa lọwọ wọn, ọga naa ko fesi, o kan bẹrẹ si i da awọn dukia wa pada ni, pẹlu kọmputa ati foonu mi. O ni ka ma binu, awọn ọmọ ‘Yahoo’ kan lawọn n wa kiri.

Ṣe bawọn EFCC ṣe n ṣe iṣẹ wọn ree? Bawo ni wọn ṣe de ile wa? Ta lo sọ fun wọn pe ki wọn wa? Gbogbo ẹ ko ye mi rara. Ọlọrun lo ni ki mama mi wa wa nibi lasiko naa.”

Bẹẹ ni Nora royin ohun toju ẹ ri.

Leave a Reply