Faith Adebọla
Titi dasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, inu ipade pataki kan lawọn gomina mọkandinlogun iha Ariwa Naijiria, ati awọn ọba alaye wọn wa niluu Kaduna, ipade pajawiri ni, wọn si tilẹkun mọri ṣe e ni, ọrọ lori awuyewuye to n ja ranyin lori owo-ori ọja, Value Added Tax, ati ofin ifẹranjẹko lawọn ipinlẹ Guusu ni apero naa da lori.
Ọpọ lara awọn gomina naa ni wọn ti tete de sipade naa, eyi to waye ni ile ijọba ipinlẹ Kaduna, Sir Kashim Ibrahim Government House, lolu-ilu ipinlẹ Kaduna.
Alaga ipade naa, to tun jẹ alaga awọn gomina ọhun, Gomina Simon Lalong ti ipinlẹ Plateau, ninu ọrọ ikini kaabọ to sọ fawọn ẹlẹgbẹ rẹ, o ni ipade naa maa jẹ kawọn le forikori lori awọn ọrọ to takoko nipa ofin ifẹranjẹko ni gbangba tawọn ipinlẹ iha Guusu kan ti ṣe nipinlẹ wọn, ati awuyewuye to n lọ lori aṣẹ ile-ẹjọ lori owo-ori ọja tawọn ipinlẹ kan lawọn fẹẹ maa gba.
Lalong tun ni ipade naa maa ṣagbeyẹwo ibi ti ọrọ aabo agbegbe naa de duro, awọn yoo si pinnu igbesẹ to kan.
Sultan tilu Sokoto, Alaaji Sa’ad Abubakar kẹta, lo lewaju awọn ọba alaye yooku onipo ki-in-ni yooku lapa Oke-Ọya lọ sipade naa.
Ireti wa pe lẹyin ipade ọhun, wọn yoo fi ipinnu ati erongba wọn lede.