Faith Adebọla
Bii ẹni n wo ere ori itage lọrọ jọ ni kootu kọkọkọkọ ‘Grade C’ kan to wa niluu Isẹyin, nijọba ibilẹ Isẹyin, ipinlẹ Ọyọ, nigba ti obinrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Abilekọ Toriọla Suliat, sọ pe ko sohun to buru ninu bi ọkọ oun ṣe fẹẹ kọ oun silẹ o, ṣugbọn afi ko kọkọ da ibale oun to gba nigba tawọn di lọkọ-laya pada, o si gbọdọ da ọmu oun pada si bo ṣe ba a nigba naa, tori ọmu oge loun gbe wọ ile rẹ.
Ọkọ Suliat, Ọgbẹni Lateef Toriọla, lo ti kọkọ mu ẹsun iyawo rẹ wa si kootu naa, to si bẹbẹ pe kile-ẹjọ tu awọn ka, latari bi iyawo oun ṣe n yẹyẹ oun ni gbangba lọpọ igba.
Ọkunrin naa ṣalaye pe ko sibi tiyawo oun ko ti le ri oun fin, titi kan ibiiṣẹ ati lode ariya lo maa n wọ oun nilẹ, to si maa n dojuti oun laarin awọn ọrẹ ati mọlẹbi kaakiri. O lọrọ naa ti su oun, iwa iyawo naa si ti pin oun lẹmi-in debii pe niṣe loun sa jade nile fun un, toun o si to ẹru ti i yọju sile tawọn idile oun n gbe mọ.
Nigba ti olujẹjọ, Abilekọ Suliat, n ṣalaye lati fesi sawọn ẹsun wọnyi, o ni latilẹ ni igbeyawo awọn ti wọ, tori oogun abẹnu gọngọ lọkọ oun fi fẹ oun, ki i ṣe ifẹ-inu oun rara.
“Ti ki i ba ṣe oogun to fi fẹ mi ni, nibo nipade ọlọja ati asiwin emi ati iru ọkunrin bii eyi.
Ṣebi aajo ni mo fẹẹ ṣe lori okoowo mi, ti mo si fọrọ lọ ọ ko too sọ pe oun le ran mi lọwọ, o ni ki n ge diẹ wa ninu irun abẹ mi, mo si ṣe bẹẹ, lẹyin naa lo ba mi sun, ba a ṣe di tọkọ-taya niyẹn.
Nigba ti mo ko dele ẹ, okoowo mi gberu si i loootọ, owo tiẹ naa si rugọgọ si i, ẹẹmeji lẹyin naa la ti tun aajo yii ṣe, afi bo ṣe di pe mo bẹrẹ si i ru, mo n gbẹ, ara mi o ya, ohun ti mo dẹ maa ri lẹyin naa ni pe o ko jade nile fun mi, ni o ba wale mọ, afi igba ti mo ri iwe ipẹjọ ati ikọsilẹ ti wọn fi jiṣẹ fun mi.
Ẹ ba mi sọ fun un pe ko da mi pada si bo ṣe ba mi nigba ta a pade, oun lo gbabale mi, ẹ ni ko da a pada, ko si da ọmu mi pada si ọmu oge to wa, ara mi gbọdọ ya daadaa pẹlu, igba yẹn lo too le kọ mi silẹ, ki kaluku maa lọ n lọ ẹ.
Adajọ ile-ẹjọ naa, Oloye Raheem Adelọdun, sọ pe oun yoo ṣi so ẹjọ yii rọ na ki ara olujẹjọ naa le tubọ mokun si i.
O paṣẹ pe kawọn mọlẹbi tọka-taya naa tete gbe igbesẹ lati tọju Suliat, ki ara rẹ le tete ya, ki wọn si jẹ kile-ẹjọ gbọ bi itọju naa ba ṣe lọ si lọjọ mẹẹdogun mẹẹdogun titi tile-ẹjọ yoo fi pinnu asiko ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.