Akeredolu gbe aba eto isuna ọdun to n bọ lọ siwaju awọn aṣofin

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Aba eto isuna oni biliọnu mọkanlelaaadọwaa Naira (#191b) ni Gomina Rotimi Akeredolu ti gbe kalẹ niwaju awọn asofin ipinlẹ Ondo gẹgẹ bii owo tijọba fẹẹ na lọdun to n bọ.

Kọmisanna feto inawo, Ọgbẹni Wale Akintẹrinwa, to lọọ ṣoju gomina niwaju awọn aṣofin lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. O ni o to bii idamẹwaa owo tijọba n gbero ati na lọdun to n bọ (2022) fi ju ti ọdun ta a wa yii lọ.

Akintẹrinwa ni nnkan bii ọgọrin biliọnu Naira o din diẹ ninu owo eto isuna ọhun nijọba Akeredolu yoo na fun awọn akanṣe isẹ tuntun ti wọn fẹẹ dawọ le, nigba ti biliọnu mejilelọgọrun-un o le diẹ to ku wa fun pipari awọn iṣẹ ti wọn n ṣe lọwọ.

O ni ijọba ti pinnu lati wa owo to to bii biliọnu mẹrinlelogoji Naira si i lọnakọna, ki awọn isẹ idagbasoke ati ipeṣe isẹ fawọn ọdọ eyi tijọba ti bẹrẹ rẹ ma baa dawọ duro.

Abẹnugan ile, Ọnarebu Bamidele Ọlẹyẹlogun, lo tẹwọ gba aba eto isuna ọhun lọwọ aṣoju gomina, to si gbe e fun alaga igbimọ to n ri ṣeto isuna nileegbimọ aṣofin ọhun, Ọnarebu Sunday Ọlajide, fun igbesẹ to yẹ.

 

Leave a Reply