Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Kootu Ko-tẹ-mi-lọrun to wa niluu Akurẹ ti bẹrẹ ijokoo lori ẹjọ ti oludasilẹ ijọ Sọtitobirẹ lagbaaye, Wolii Alfa Samuel Babatunde, pe ta ko idajọ ẹwọn gbere ti wọn da fun oun atawọn ọmọ ijọ rẹ marun-un lọdun to kọja.
Igbimọ olugbẹjọ ọhun, eyi ti Onidaajọ Rita Rosakhare Pemu jẹ alaga rẹ ni wọn pade lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lati gbọ awijare Wolii Alfa lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o mọ nipa ọmọ ọdun kan, Gold Kọlawọle, to sọnu ninu sọọsi rẹ lọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun 2019.
Wolii Alfa ninu awijare rẹ rọ igbimọ olugbẹjọ naa lati fagi le idajọ ẹwọn gbere ti wọn da fun oun atawọn marun-un mi-in nitori pe iya ẹṣẹ aimọdi lawọn n jẹ lọwọ.
Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ lẹyin ọpọlọpọ ariyanjiyan lati ọdọ agbẹjọro awọn olupẹjọ ati tijọba, alaga igbimọ, Onidaajọ Rita, ni oun yoo kan sawọn tọrọ kan laipẹ lori ọjọ ti awọn ba fẹnu ko si fun idajọ.