Nitori ọwọngogo maaluu, awọn alapata ko ta ẹran ni Kwra

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Wọn ni a o le tori pe a fẹ jẹran, ka pe maaluu ni bọọda, eyi lodifa fun bii ọpọ awọn alapata ko se ni ẹran maaluu lori igba ni Kwara, latari pe wọn ni maaluu ti di ọwọngogo.

 

ALAROYE, ṣabẹwo si awọn ọja kan to ṣe pataki ti wọn ti n ta ẹran, ti a si fọrọ wa awọn alapata lẹnu wo, lara awọn ọja ta a ṣabẹwo si ni ọja Mandate, nijọba ibilẹ Iwọ -Oorun (West) Ilọrin, nibi ti gbajumọ alapata kan ti orukọ rẹ n jẹ Alufaa ti sọ pe gbogbo ibi ti wọn ti n pa ẹran niluu Ilọrin loun de, ti wọn ko si pẹran latari ọwọn gogo maaluu.

Bakan naa ni ọja Irewọlede, niluu Ilọrin, ọkunrin kan to n jẹ Abu Olowo, to n ta ẹran sọ pe ẹran ti wọn lasiko yii, to si jẹ pe ẹran maaluu kilo kan ti wọn n ta ni ẹgbẹrun kan dabọ naira lo ti di ẹgbẹrun meji abọ bayii. O ni bi maaluu ba ṣe tobi si ni wọn ṣe n padanu owo lori ẹ sì.

Akọwe ẹgbẹ awọn alapata ni agbegbe Akerebiata, Alaaji Ọba Elegede, sọ pe ohun to fa ọwọngogo ẹran maaluu ko sẹyin pe maaluu gan-an fun ra ẹ wọn lasiko yii, bakan naa, ko tun si ọja, eyi to waa buru nibẹ ni pe laipẹ yii ti awọn ọmọ ẹgbẹ alapata gbera lati lọọ ra maaluu nipinlẹ Niger, awọn ajinigbe ji wọn gbe, ti ẹgbẹ si san obitibiti owo ki wọn too tu wọn silẹ. O tẹsiwaju pe maaluu ti wọn n ra ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira ti di ẹgbẹrun lọna igba ataabọ naira bayii.

Akọwe ẹgbẹ ọhun fi kun un pe lasiko yii, wọn o le wa maaluu lọ sibi to jin bii Maiduguri ati ipinlẹ Yobe mọ nitori awọn ajinigbe, sugbọn awọn ẹṣẹkuku nipinlẹ Kwara ni wọn ti n ra ọja bii Ilesha Baruba, Kaiama, Ajaṣẹ, Sharẹ, Bode Saadu, Jẹbba ati Igbeti, nipinlẹ Ọyọ.

Leave a Reply