Adefunkẹ Adebiyi
Chekwume Malvin lọkunrin yii n jẹ, ọmọ Naijiria wa nibi ni, ṣugbọn orilẹ-ede India lo n gbe to si ti n ṣiṣẹ tiata. Afi bi wọn ṣe ka oogun oloro mọ ọn lọwọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021 yii, n lawọn ọlọpaa India ba fọwọ ofin mu un.
Ibi kan ti wọn n pe ni BDA Complex, lagbegbe HRBR, ni India, lọwọ ti ba Chekwume, ọmọ Ibo to ti kopa ninu fiimu India bii ogun (20), nitori wọn lo lọ sile ẹkọ fiimu New York Film Academy, ni Mumbai, o si kọkọ kẹkọọ nipa iṣẹ fiimu ọhun l’Abuja, ko too di pe o sọda si India.
Bawo lo ṣe waa jẹ to fi di pe wọn ba egboogi oloro lọwọ ọkunrin yii, awọn ọlọpaa K’G Halli ti wọn mu un ṣalaye pe Malvin loun fẹẹ tete lowo ni.
Fisa awọn to fẹẹ waa gba itọju ni India ni Chekwueme gba to fi de ilu naa, nigba to ya lo lọ sileewe fiimu to fi di pe o n ṣiṣẹ tiata nibẹ, ko too waa di pe ọwọ tẹ ẹ fun egbogi oloro gbigbe yii.