Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai ti sọ pe awọn gomina ipinlẹ Ariwa ko lodi si ki iha Guusu fa aarẹ kalẹ lọdun 2023, ṣugbọn ki i ṣe ọna to yẹ kawọn gomina iha naa tọ ni wọn tọ yẹn, o lo yẹ ki wọn kọkọ ba awọn gomina Ariwa sọrọ, ki wọn jọ fori kori naa lori ọrọ naa naa, ki wọn too maa gbe ipinnu kalẹ.
Nigba ti El-Rufai n ba awọn oniroyin sọrọ l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, lọfiisi rẹ ni Kaduna, lo ṣalaye pe ipinnu tawọn gomina Ariwa fẹnu ko le lori ninu ipade ti wọn ṣe lọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii, ki i ṣe ọna to yẹ kawọn gomina Guusu gbe ọrọ gba ni wọn gba yẹn.
“A o sọ pe ki ipo aarẹ ma lọ sibomi-in, o le lọ sagbegbe mi-in, ṣugbọn o yẹ ki wọn kọkọ wa, ki wọn jokoo pẹlu awọn oloṣelu apa Oke-Ọya, ka jọ sọrọ papọ, ka si jọ wo bi a ṣe le kin Guusu lẹyin, ki i ṣe ki ẹnikan kan jokoo si Eko tabi Port-Harcourt, ko maa paṣẹ pe boya Ariwa fẹ tabi wọn o fẹ o, wọn gbọdọ da agbara pada sagbegbe Guusu ni, iyẹn o boju mu rara, ki i ṣe bi wọn ṣe n ṣe oṣelu niyẹn, koda iwa omugọ niyẹn.”
El-Rufai tun ṣalaye pe ki i ṣe igba akọkọ ree tawọn eeyan Oke-Ọya maa ṣatilẹyin fun aarẹ to jade lati iha Guusu, o ni tinutinu ni wọn dibo fun aarẹ ana, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, lẹẹmeji, lọdun 1999 ati 2003.