Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọkan-o-jọkan awuyewuye lo ti n waye latari bi Deji tilu Akurẹ, Ọba Ogunlade Aladeyoyinbo Aladelusi, ṣe kede titi awọn ọja pa nitori eto isinku Ọnarebu Adedayọ Ọmọlafẹ, ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin to ku lojiji ni nnkan bii oṣu meji sẹyin.
Ọjọruu, Wẹsidee ọsẹ yii ni Michael Adeyẹye to jẹ Akọwe iroyin fun Deji fi atẹjade kan sita lorukọ kabiyesi, ninu eyi to ti kilọ fawọn ọlọja atawọn to ni ṣọọbu jake-jado Akurẹ lati ma ṣe taja lọjọ Ẹti, Furaidee, ti wọn fẹẹ ṣayẹyẹ eto isinku gbajugbaja oloṣelu ọmọ bibi ilu Akurẹ ọhun.
Ọba Aladeyoyinbo ni gbogbo eeyan ilu lo gbọdọ ya ọjọ naa sọtọ lati fi bu ọla ikẹyin fun Oloogbe Ọmọlafẹ latari ipa ribiribi to ti ko sẹyin nigba aye rẹ.
Kete ti iroyin yii ti jade lawọn eeyan ti n gba a bii ẹni gba igba ọti lori ẹrọ ayelujara, bawọn kan ṣe n kan saara si Deji lori aṣẹ to pa ọhun lawọn mi-in n binu pe ọrọ ọja atawọn ṣọọbu titi pa nigboro Akurẹ ti n di lemọlemọ.
Obinrin oniṣowo kan to wa ninu awọn tinu n bi, ṣugbọn ta a forukọ bo lasiiri ni o ti to bii igba mẹta ọtọọtọ ti iru aṣẹ yii n jade laarin oṣu diẹ sira wọn.
O ni o yẹ ki Deji din bo ṣe n paṣẹ titi ọja atawọn ṣọọbu pa ku, nitori pe Akurẹ ki i ṣe ilu kan ṣaa to yẹ kiru nnkan bẹẹ ti maa waye ni gbogbo igba.
Yatọ sawọn alejo to n gbe niluu Akurẹ ti igbesẹ naa le ṣajeji si, o ni o ṣee ṣe ko tun ṣakoba fun eto ọrọ-aje awọn eeyan ati tijọba.
Bi ọpọlọpọ awọn eeyan ṣe n kan saara si obinrin to sọrọ yii pe ododo ọrọ lo sọ lawọn mi-in n kin Deji lẹyin pe ko sohun to buru ninu aṣẹ to pa naa.
Agbẹjọro kan to filu Akungba Akoko ṣebugbe ni Ọba Aladelusi ko ti i ṣaṣeju pẹlu aṣẹ to pa pe kawọn eeyan ilu bu ọla fun ọkan ninu wọn latari iṣẹ nla to ti ṣe ṣaaju laarin wọn.
Bakan naa lo fi ye awọn eeyan pe jijẹ olu ilu ipinlẹ Ondo Akurẹ ko gbọdọ di awọn olugbe ibẹ lọwọ lati bọwọ fun aṣa ati iṣe ilu nitori pe ilu kọọkan lo ni aṣa isẹdalẹ tirẹ.