Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun fẹyinti layaajọ Ominira Naijiria

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ọdun 2021 yii, iyẹ ọjọ ti Naijiria pe ẹni ọdun mọkanlelọgọta to ti gba ominira ni Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward Awolọwọ Ajogun, naa fẹyinti lẹnu iṣẹ ọlọpaa, nitori oun naa ti pe ẹni ọgọta ọdun laye, ọjọ naa ni iṣẹ rẹ si pari ninu iṣẹ ọlọpaa ilẹ wa.

Ọmọ Akoko-Edo, nipinlẹ Edo, ni ọga ọlọpaa Ogun tẹlẹ yii, ọdun 1988 lo darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa, iṣẹ naa si ti gbe e kaakiri ipinlẹ Naijiria ko too fi eto gbogbo rọ si ipinlẹ Ogun yii. Ọdun 2019 ni Ajogun di kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun.

Lati ṣayẹyẹ imọriri ati ifarajin ọkunrin naa nipinlẹ Ogun, nipa bo ṣe ṣiṣẹ takuntakun, tọwọ si ba ọpọlọpọ awọn oniṣẹ ibi nipinlẹ yii, ayẹyẹ ọlọjọ meji ni wọn ti ya sọtọ.

Awọn afẹnifẹre yoo ṣe ọkan fun un nile igbafẹ awọn ọlọpaa to wa ni GRA, Ibara, l’Abẹokuta, layajọ ọjọ ibi rẹ yii gan-an, to ba si di lọjọ keji, oṣu kẹwaa, awọn ẹgbẹ PCRC ti wọn n ba ọlọpaa ṣọrẹ yoo tẹ pẹpẹ faaji tiwọn fun un ni Valleyview Government House, Abẹokuta.

Leave a Reply