Ọdun keji ree ti Adebayọ ti n ba ọmọ to bi lo pọ ni Matọgun, niyẹn ba kọwe ifisun sọlọpaa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Fun pe o n ko ibasun to le fun ọmọ bibi inu ẹ lati ọdun meji sẹyin, Adebayọ Akinrinoye ti wa lẹka to n ri si iṣẹlẹ bii eyi lọdọ awọn ọlọpaa, ni Ọta, nipinlẹ Ogun.

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021 yii, lọwọ awọn ọlọpaa teṣan Agbado, nipinlẹ Ogun, tẹ Adebayọ, ẹni ọdun mejilelaaadọta (52). Ọmọ rẹ obinrin ti ọjọ ori ẹ ko ju mẹrindinlogun lọ (16) lo kọwe ifisun si teṣan naa pẹlu alaye pe ọmọ ọdun mẹrinla loun wa ti baba oun ti n ba oun sun.

Ọmọbinrin naa ṣalaye pe latigba naa lo ti n ṣere buruku ọhun pẹlu oun titi dasiko yii toun jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun. O ni gbogbo ipẹ toun mọ loun ti ṣe fun baba oun pe ko yee ba oun lo pọ, ṣugbọn ko gbọ, erekere naa ti wọ ọ lara ju ohun to le fi silẹ lọ, ohun to jẹ koun kọwe sawọn ọlọpaa ree, ki wọn le gba oun lọwọ rẹ.

DPO teṣan Agbado, CSP Kẹhinde Kuranga, ran awọn ikọ rẹ lọ si Ojule kọkanla, Opopona  Kabiru, Matọgun/Agbado, ti Adebayọ ati ọmọ rẹ n gbe, nibẹ ni wọn si ti fọwọ ofin mu un, ti wọn gbe e lọ si teṣan.

Nigba to de teṣan, Adebayọ jẹwọ pe loootọ loun n ba ọmọ oun sun, ṣugbọn niṣe lo bẹrẹ si i bẹ ọmọbinrin naa pe ko ma binu, ko foriji oun.

Wọn ti gbe baba yii lọ sẹka to n ri si ọrọ mọlẹbi, lọdọ awọn ọlọpaa Ọta, nipinlẹ Ogun.

Leave a Reply