Faith Adebọla, Eko
O kere tan, eeyan mẹrin lo ti pade iku ojiji, ti ọpọlọpọ si fara pa nibi ijamba ina ẹlẹntiriiki to papọ mọ afẹfẹ gaasi idana lọjọ Aiku, Sannde yii, nibi isin ajọdun ṣọọṣi Kerubu El-Adonai Evangelical Ministry, l’Abule-Ẹgba, l’Ekoo.
Iṣẹlẹ ọhun la gbọ pe o waye ni nnkan bii aago mẹjọ owurọ nileejọsin naa to wa ni Ojule kejidinlogun, ọna Jibiwu, nikọja ọna Agbe, nibudokọ U-Turn, to wa l’Abule-Ẹgba.
Wọn ni aṣọ funfun ti wọn fi ṣe asia to wa niwaju ṣọọṣi naa ni wọn fẹẹ paarọ, tori eyi to wa nibẹ tẹlẹ ti gbo, ni wọn ba gbe akaba, wọn si hu opo onirin ti wọn fi ṣe asia naa.
Eyi ni wọn n ṣe lọwọ ti opo naa fi yẹ mọ awọn to di i mu lọwọ, o si fara kan waya ina to fana wọnu ṣọọṣi ọhun, waya ina naa ṣa’na parapara bo ṣe n ja walẹ, o si ja le afẹfẹ gaasi ti wọn fi n dana ounjẹ ajọdun lọwọ, ni gaasi naa ba bu gbamu.
Loju-ẹsẹ lawọn gende mẹfa ti na gbalaja silẹ, ṣugbọn nigba tawọn oṣiṣẹ panapana Eko (Lagos State Fire and Rescue Service) atawọn oṣiṣẹ ajọ onina ẹlẹntiriiki Eko debi iṣẹlẹ naa, wọn doola ẹmi awọn meji lara wọn, nigba tawọn mẹrin ti ku patapata.
A gbọ pe ọgọọrọ eeyan lo fara pa nigba tọrọ di bo-o-lọ-o-yago, nibi ti wọn si ti n sapa lati sa jade ni wọn ti ṣe ara wọn leṣe.
Ọga agba ileeṣẹ panapana Eko, Abilekọ Margaret Adeṣẹyẹ, sọ f’ALAROYE lori aago pe ambulansi pajawiri ti ko awọn to fara pa lọ sọsibitu ijọba lati tete ri itọju gba, o ni iwa aibikita awọn onile-ijọsin naa lo ṣokunfa iṣẹlẹ yii.
O lawọn oṣiṣẹ ajọ awọn ti ko opo to ṣubu sọna kuro lati ma ṣediwọ fun lilọ bibọ ọkọ, wọn si ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii.