Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ awọn onimaalu ti wọn n pe ni Miyetti Allah ti n halẹ pe awọn yoo gbe awọn gomina ipinlẹ Ondo, Eko atawọn ojugba wọn lawọn ipinlẹ ni agbegbe Guusu ilẹ wa ti wọn fọwọ si ofin fifi maaluu jẹko ni gbangba lo sile-ẹjọ, sibẹ, awọn gomina yii ti ni awọn ṣetan lati sọ tẹnu awọn, kawọn si fi ofin daabo bo igbesẹ ti awọn gbe naa.
Lasiko ti Akọwe agba ẹgbẹ naa, Selah Alhassan n ba iweeroyin Punch sọrọ lo sọ pe gbogbo iwe to yẹ lawọn ti n ko jọ, ko si ni i pe rara tawọn yoo fi pe awọn gomina to ṣe ofin ki wọn ma fi maaluu jẹko ni gbangba yii lẹjọ.
Ọkunrin naa ni ofin ti wọn ṣe yii ofin eṣu, to si ni ọrọ oṣelu ninu. O ni iru ofin bayii ko wa lati mu ki alaafia jọba ni orileede wa, nitori wọn jẹ ofin to mu ikoriira lọwọ, to si tun ni ọrọ oṣelu ninu, bẹẹ lo jẹ ofin asitaani patapata.
Saleh ni awọn ko ri ohunkohun to daa ninu ofin naa, ati pe bi awọn gomina yii ṣe gun le lilo ofin yii, Ọlọrun ko ni i jẹ ki wọn ṣaṣeyọri rara nitori pe awọn ti ko mọ nnkan kan ni awọn darandaran ti wọn n tori ẹ ṣofin yii.
O waa ke si ijọba lati ri i pe ofin yii ko ṣiṣẹ nitori ofin to le ba ọrọ aje ilẹ wa jẹ ni gẹgẹ bo ṣe sọ. O ni ki Aarẹ ilẹ wa, awọn aṣofin tete ke si awọn gomina yii ki wọn tọwọ ọmọ wọn bọṣọ lori ofin ti wọn ṣe naa.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni awọn gomina lati apa iha Guusu ṣepade kan niluu Eko, nibi ti wọn ti fẹnu ko pe gbogbo awọn gomina yii ni wọn gbọdọ fọwọ si ofin ma fi maaluu jẹko ni gbangba kaakiri awọn ipinlẹ wọn.
Eyi lawọn gomina naa bẹrẹ si i ṣe, ti ọpọ ninu wọn si ti gbe aba naa lọ ṣọdọ awọn aṣofin, ti wọn ti fọwọ si i, ti awọn gomina paapa ti buwọ lu u. To si ti dofin pe ko si aaye fifi maaluu jẹko ni gbangba kaakiri awọn ipinlẹ wọn, eyi ti ko yọ ilẹ Yoruba silẹ.
Ibi ti ọrọ naa yoo ja si lawọn onwoye n wo.