Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ, totun jẹ adari ileegbimọ aṣofin agba tẹlẹ lorileede Naijiria, Sẹnetọ Bukọla Saraki, ṣafihan kaadi rẹ lẹyin to forukọsilẹ ni Wọọdu Ajikobi, nijọba ibilẹ Iwọ Oorun (West) Ilọrin, nipinlẹ Kwara. Lẹyin eyi lo kopa nibi eto idibo, nibi ti wọn ti yan awọn oloye ẹgbẹ kaakiri ijọba ibilẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ninu ọrọ Saraki, o ni pẹlu bo ṣe jẹ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ni ẹgbẹ oṣelu alatako kan gboogi nipinlẹ Kwara, to si tun jẹ pe inu ẹgbẹ naa ni iṣọkan ati alaafia ti n jọba ju, eyi ṣafihan pe ẹgbẹ oṣelu naa yoo jawe olubori, ti yoo si gbakoso iṣejọba pada ni Kwara, nibi eto idibo gbogbogbo ti yoo waye lọdun 2023. Saraki tẹsiwaju pe ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa nireti pe wọn yoo gbakoso iṣejọba pada, ti wọn yoo si gbe oludije to kunju oṣunwọn kalẹ lọdun 2023.
Bakan naa lo juwe eto iforukọsilẹ ti ẹgbẹ ọhun ṣe gba lori ayelujara gẹgẹ bii eyi to dara ju lọ, ati pe ẹgbẹ naa ti ṣetan lati jẹ ki awọn ọdọ ati awọn obinrin ni anfaani lati kopa ninu eto ẹgbẹ.