Adefunkẹ Adebiyi
Oro to o da mi ni mo da ọ lawọn ẹgbẹ Fulani darandaran ti wọn n pe ni Miyetti Allah Kautal Hore fẹẹ fi ọrọ wọn ṣe o. Ẹgbẹ naa ti ni awọn ko ni i ṣatilẹyin kankan fun ẹnikẹni to ba fẹẹ dupo aarẹ lati iha Guusu, ti tọhun si ti ṣofin ma-fẹran-jẹko laduugbo rẹ. Wọn ni laye yii kọ lawọn yoo ti ondije bẹẹ lẹyin, ka ma ri i.
Saleh Alhassan, Alukoro ẹgbẹ awọn Miyetti Allah yii lo jiṣẹ ti gbogbo ẹgbẹ ran an lọjọ Iṣẹgun, ọjọ karun-un, oṣu kẹwaa yii, nigba to n ba iwe iroyin Punch sọrọ lori ẹka ayelujara.
Alukoro wọn naa ṣalaye pe ofin buruku, ofin ẹlẹmi Eṣu, to si ni ọwọ kan oṣelu ninu ni awọn gomina Guusu ti wọn fẹnuko si ma-fẹran-jẹko yii ṣe.
Saleh ni ohun ti awọn gomina Guusu yii n ṣe ye awọn o, awọn mọ pe ete lati gba ijọba Naijiria ni 2023 ni wọn n da.
O ni gbogbo awọn lawọn mọ pe awọn gomina Guusu fẹẹ fọgbọn le awọn gomina ilẹ Hausa lere ni, nitori ẹ ni wọn ṣe n ṣofin onikumọ ti ko pe awọn yii, ti wọn ni awọn ko gbọdọ fẹran jẹko ni gbangba.
Saleh ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe ko sohun to kan ẹgbẹ awọn pẹlu ẹya ti yoo gba ipo aarẹ ni 2023, o ni ṣugbọn oun mọ pe awọn to fẹẹ gba ijẹ lẹnu awọn yii, ti wọn ni kawọn ma ṣiṣẹ oojo awọn yii, awọn ko ni i ṣe tiwọn naa, nitori wọn ko ro rere ro awọn rara pẹlu ofin ti wọn ṣe.
“Bi ẹ ba lọọ mu ẹnikan bii Akeredolu ipinlẹ Ondo wa pe ka dibo fun si ipo aarẹ, a o ni i ti i lẹyin laelae, nitori ọna bi tiwa yoo ṣe bajẹ loun n wa ni tiẹ. Awọn eeyan bii oun yẹn, a o le ti wọn lẹyin, gbogbo ẹni to ba ti n ba awọn Biafra dọwẹẹkẹ, a o ni i dibo fun un” Bẹẹ ni Saleh wi lorukọ ẹgbẹ wọn, Miyetti Allah.
Ṣe ẹẹmeji laarin ọdun yii ni awọn gomina iha Guusu ti ṣepade, awọn mẹtadinlogun naa si fẹnuko pe awọn Fulani ko gbọdọ fẹran jẹko lọdọ awọn mọ.Wọn tun ni iha Guusu lo yẹ ko pese aarẹ Naijiria ni 2023.
Ohun to mu awọn gomina mọkandinlogun lati ilẹ Hausa naa sare ṣepade laipẹ yii niyẹn, ti wọn ni awọn ko fara mọ aba awọn ti Guusu yii rara, wọn ni bi ẹyẹ ba ṣe fo lawọn yoo ṣe sọko ẹ. Ọrọ naa ṣi wa nilẹ titi dasiko yii.