Nibi ti ọmọkunrin yii ti fẹẹ ta ọmọ ọlọmọ to ji gbe lọwọ ti tẹ ẹ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

.Ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan, Samuel Lucky Akpan, nibi to ti n ṣeto ati lu ọmọdekunrin kan ta ni gbanjo.

ALAROYE gbọ pe inu ṣọọbu kan to wa lagbegbe Alagbaka, ni Akpan ti ji ọmọ ọdun mẹrin ọhun gbe, to si fẹẹ lọọ ta a fun ọrẹ rẹ kan, ẹni ti wọn ti jọ dunaa dura tẹlẹ lori iye owo to fẹẹ ta ọmọ ọlọmọ.

Asiko to n fa ọmọdekunrin naa lọ sibi to fi adehun si pẹlu ẹni to fẹẹ ra a lọwọ rẹ lawọn oṣiṣẹ ẹsọ Amọtẹkun kan pade rẹ, ti wọn si da ibeere bo o lori ibi to n mu ọmọ ọwọ rẹ lọ.

Airi esi gidi fun wọn nipa awọn nnkan ti wọn beere lọwọ rẹ ni wọn fi mu un lọ si ọfiisi wọn, nibi to ti pada jẹwọ fun wọn pe ṣe loun ji ọmọ naa gbe lati lọọ ta a fun ẹnikan ni ẹgbẹrun lọna igba Naira (#200,000).

Akpan funra rẹ ko jiyan tabi purọ lori ẹsun ti wọn fi kan an, o ni anfaani ọrẹ ti oun jẹ si awọn ẹbi ọdọmọkunrin ọhun loun lo ti oun fi raaye ji i gbe ninu ṣọọbu iya rẹ.

Ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Akwa Ibom ọhun ni ọjọ pẹ diẹ ti oun ti n ṣiṣẹ ajinigbe, ewe kan lo ni oun maa pọfọ si, ti oun yoo si fi le ẹnikẹni ti oun ba fẹẹ ji gbe lori, eyi ti ko ni i jẹ ki onitọhun mọ nnkan kan mọ titi yi yoo fi di tita fawọn to fẹẹ lo o.

Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni afurasi naa ko ni i pẹẹ foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.

 

 

Leave a Reply