Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Arole Oduduwa, to tun jẹ Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja II, ti ke si gbogbo awọn oloṣelu nipinlẹ Ọṣun ati awọn alatilẹyin wọn lati gba alaafia laaye, ṣaaju, lasiko ati lẹyin eto idibo gomina to n bọ.
Ọọni Ogunwusi parọwa yii lasiko ti ọkan lara awọn oludije funpo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ṣabẹwo si aafin rẹ ni Ile Oodua, ni Ileefẹ.
Kabiesi woye pe ọpọlọpọ wahala to maa n ṣẹlẹ lasiko idibo ti a ti ṣe sẹyin lorileede yii ko ṣẹyin iwa awọn to n tẹle awọn oloṣelu.
Gẹgẹ bi Ọba Adeyẹye ṣe sọ, “Ẹyin ololufẹ awọn oloṣelu yii lẹ maa n dari ọkan awọn adari yin. Mo fẹẹ rọ yin lati fi iwa ọmọluabi han nitori abayọri si wahala ati rogbodiyan ki i dara.
“Ẹ dẹkun titi awọn adari nitikuti ti awọn yẹn naa aa fi maa ṣeleri asan ti wọn ko ni i le mu ṣẹ. Ẹ ṣe oloootọ ati alaapọn ni gbogbo igba, yoo si dara fun yin”
Ṣaaju ninu ọrọ rẹ, Sẹnetọ Adeleke ṣapejuwe Ọọni gẹgẹ bii baba to ṣee mu yangan. O bu ẹnu atẹ lu ipo ti awọn oju-ọna ilu Ileefẹ wa ati bi ko ṣe si awọn nnkan amayedẹrun gbogbo nibẹ.
Adeleke sọ pe ti oun ba le lanfaani lati de ipo gomina, oun yoo mu iyipada ba ọpọlọpọ nnkan nitori oun gbagbọ pe ibi ọwọ ni Ileefẹ ati ipo Ọọni jẹ.
O sọ siwaju pe pẹlu erongba oun lati da Papakọ ofurufu tipinlẹ Ọṣun silẹ, oun yoo wa jẹẹti aladaani kan (Private Jet) ti yoo maa gbe Ọọni kaakiri ibi gbogbo to ba fẹẹ lọ.
Adeleke ṣalaye pe ohun kan pato to mu ifasẹyin ba gbogbo nnkan nipinlẹ Ọṣun ko ṣẹyin bijọba ṣe di ọwọ mọ owo awọn ijọba ibilẹ, ti wọn ko jẹ ki wọn le se ohunkohun, o si ṣeleri pe gbogbo eleyii ni yoo yipada lọdun to n bọ.
Ọbalufẹ, Ọba Idowu Adediwura, ninu ọrọ tirẹ, rọ Adeleke lati ṣiṣẹ tọ awọn ileri rẹ lẹyin, ki gbogbo rẹ ma baa jẹ lori irọ lasan gẹgẹ bi awọn oloṣelu kan ṣe ṣe sẹyin.
Bakan naa ni Lọwa Adimula ti Ifẹ, Oloye-Agba Adekọla Adeyẹye, pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Ileefẹ nija lati maa beere abọ iṣẹ iriju awọn adari wọn loorekoore nitori awọn araalu n wo wọn.