Faith Adebọla, Eko

Yoruba bọ, wọn ni afago kẹyin aparo, ohun oju wa loju n ri. Owe yii lo ṣẹ mọ ọkunrin tẹnikẹni o ti i mọ orukọ ẹ yii, iṣẹ adigunjale ni wọn lo n ṣe, ṣugbọn bebe iku loun ti lọọ jale tiẹ, ibi to ti n gbiyanju lati ge waya ẹrọ amunawa ti wọn n pe ni transformer lagbegbe Surulere lo ti gan mọ’na, lo ba ku fin-in fin-in.

Transfọma kan to wa laduugbo Eric Moore, lagbegbe Surulere, nipinlẹ Eko, la gbọ pe gende yii lọọ ba ṣerekere ọhun l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, tiṣẹlẹ naa waye. Wọn loun atawọn kan ni wọn maa n lọọ ji waya dudu kan ti wọn lo wọn owo gidi lara eroja transifọma kaakiri agbegbe naa, ọbẹ, ada, jiga ati pilaya (plier) wa lara irinṣẹ ti wọn n ko kiri, ti wọn fi n jale ọhun.

Ṣugbọn iku n jọgẹdẹ, iku n re’di, iku o mọ pohun to dun lo n pa’ni. Ọkunrin kan to ba akọroyin ileeṣẹ Punch sọrọ lori iṣẹlẹ yii ṣalaye pe fun bii ọsẹ kan lawọn eeyan agbegbe naa ti fi wa ninu okunkun latari iwa buruku awọn adigunjale wọnyi ti wọn ji waya transifọma naa lọ, o lawọn ṣẹṣẹ da owo ra waya mi-in pada ni, waya naa ni wọn tun waa ji ge lẹẹkeji tọwọ palaba wọn fi se’gi.

“Awọn oṣiṣẹ ina ẹlẹntiriiki (Eko Electricity Distribution Company) ni wọn gbe waya tuntun ta a ṣẹṣẹ ra naa wa lọjọ Aje, Mọnde, oju-ẹsẹ si ni wọn ti gbe’na le awọn waya naa, ṣugbọn o jọ pe awọn ole yii o mọ pe ina ti wa lara awọn waya naa.

Oru ọjọ ti wọn wa lati ge waya ọhun ni ina gbe ọkan lara wọn lojiji, lawọn to ku ba fẹsẹ fẹ ẹ,  a ri ipasẹ wọn ati irinṣẹ ibi ti wọn n lo, titi di nnkan bii aago mẹrin irọlẹ Ọjọbọ, ṣi ni oku ọkunrin naa fi wa nidii tiransifọma naa, bo ṣe bẹrẹ mọlẹ to n hu waya naa lọwọ lo gan mọ’na.”

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ mọnamọna Eko, Ọgbẹni Godwin Idemudia ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni loootọ niṣẹlẹ naa waye, ati pe awọn ti lọọ ṣatunṣe si waya tawọn ọbayejẹ naa fẹẹ ji ge.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, CSP Adekunle Ajiṣebutu naa sọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori awọn to sa lọ, awọn si ti gbe oku oloogbe naa lọ si mọṣuari ileewosan ijọba to wa ni Surulere.

Leave a Reply