Faith Adebọla
Iroyin to gbode kan lori atẹ ayelujara bayii ni ti aisan ojiji kan ti wọn lo kọ lu gbajugbaja ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho lọgba ẹwọn orileede Bẹnẹ to wa, wọn niṣe ni wọn gbe e digbadigba lọ sileewosan kan lati doola ẹmi rẹ.
Gẹgẹ bi Amofin Yọmi Aliu to jẹ ọkan lara awọn lọọya to n ṣoju fun Sunday Igboho nile-ẹjọ ṣe sọ fun ileeṣẹ oniroyin BBC, o ni ọkunrin naa ti dubulẹ aisan gidi lọgba ẹwọn ti wọn fi i si, aisan kindinrin ati ifun ni wọn lo kọ lu u.
Yọmi ni ọgba ẹwọn Bẹnẹ ni aisan naa ti de ba Sunday Igboho, tori ko si nnkan to jọ iru aarẹ yii lasiko ti wọn fi mu un satimọle lati nnkan bii oṣu mẹta sẹyin.
“Ko si aisan to n ṣe Igboho ki wọn too mu un ni Kutọnu, aisan to yọju yii lagbara gidi ni, niṣe ni wọn sare gbe e digbadigba lọ sileewosan fun itọju pajawiri.
Mi o le sọ boya o ti kuro nileewosan tabi boya wọn ti da a pada sọgba ẹwọn, ṣugbọn ohun ta a fidi ẹ mulẹ ni pe aisan naa lagbara, o si jọ pe kinni ọhun ti ṣakoba fun kindinrin ati ifun rẹ, mi o mọ boya o ti ṣakoba fawọn ẹya ara mi-in, mo kan mọ pe awọn ẹya ara inu lọhun-un kan ti n niṣoro.
Bakan naa ni Ọgbẹni Maxwell Adeyẹye fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni loootọ ni aisan n ṣe Oloye Sunday Adeyẹmọ, o si jọ pe kindinrin rẹ laisan naa kọ lu, ṣugbọn o ni ayẹwo mi-in ti wọn ba ṣe lo maa fidi rẹ mulẹ, ati pe awọn to kọṣẹ mọṣẹ gidi lo n bojuto ọkunrin naa lọwọ.