Jọkẹ Amọri
Nitori iroyin pe ara rẹ rẹ ko ya, ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho, ti sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe tọrọ owo lọwọ awọn eeyan nitori aisan to n ṣe oun.
O sọrọ yii ni idahun si bi awọn kan ṣe ni o n tọrọ owo, ti wọn si ni ki awọn eeyan maa dawo ti wọn yoo ko fun un lati fi tọju ara rẹ.
Nigba ti agbẹnusọ rẹ, Ọlayẹmi Koiki n sọrọ lori ahesọ naa, o ni Sunday Igboho ko tọrọ owo lọwọ ẹnikẹnni, bẹẹ ni ko bẹ ẹnikẹni lati ba a wa owo ti yoo fi tọju ara rẹ. O ni ki gbogbo awọn ti wọn n ṣe bẹẹ jawọ ninu iru iwa yii.
Ninu atẹjade kan to fi sita lo ti sọ pe agbẹjọro Igboho lo pe oun pe awọn kan ti n lọ kiri lati tọrọ owo lorukọ Igboho, ti wọn ni awọn yoo fi tọju rẹ nitori aisan ti wọn ni o n ṣe e. O ni ki awọn ti wọn n ṣe bẹẹ dawọ eleyii duro.
‘‘Loootọ ni ara Igboho ko ya, to si nilo amojuto, ṣugbọn a ko ran ẹnikẹni lati maa tọrọ owo lorukọ rẹ pe awọn fẹẹ fi tọju rẹ. A kan n rọ ijọba ilẹ Benin pe ki wọn fi i silẹ ko le raaye lọọ tọju ara rẹ ni.’’ Bẹẹ ni Koiki wi.