Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Awọn alaṣẹ Fasiti Obafemi Awolowo, Ileefẹ, ti kede pe ki awọn akẹkọọ pada sileewe ọhun lati le ṣe idanwo wọn.
A oo ranti pe ọjọ keji, oṣu kẹwaa, ọdun yii, lo yẹ ki wọn bẹrẹ idanwo ko too di pe awọn akẹkọọ ṣe ifẹhonu han lori iku to pa ọkan lara wọn, eleyii ti wọn di ẹbi rẹ ru aikasi nnkan si awọn dokita ileewosan ọgba naa.
Ṣugbọn atẹjade kan latọwọ Alukoro ileewe naa, Abiọdun Ọlarewaju, lọsan-an ọjọ Ẹti sọ pe lasiko ipade pajawiri ti awọn igbimọ iṣakoso ileewe naa ṣe ni wọn ti fẹnu ko pe ki awọn alaṣẹ ṣi ileewe naa pada.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ọjọ Furaidee to n bọ, iyẹn ọjọ karun-un, oṣu kọkanla, ni awọn akẹkọọ yoo pada sileewe, ọjọ keji ni wọn yoo si bẹrẹ idanwo wọn.
O ni ilana idanwo to ti wa nilẹ tẹlẹ fun ẹkajẹka ni wọn yoo tẹle ni kete tidanwo ba ti bẹrẹ.
Ọlarewaju fi kun ọrọ rẹ pe, Ọga agba fasiti naa, Eyitọpẹ Ogunbọdẹde, ti ke si awọn obi ati alagbatọ lati kilọ fun awọn ọmọ wọn ti wọn ti pari idanwo ki wahala naa too ṣẹlẹ lati jokoo sile titi digba ti awọn ti wọn fẹẹ bẹrẹ idanwo yoo fi pari.