Faith Adebọla
Bi ko ba si ti kokoro buruku ti ki i jẹ ka gbadun obi to gbo ni, bi ko si ti iku to yọwọ gbajugbaja ajafẹtọọ ọmọniyan ati agbẹnusọ tẹlẹ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre nni, Yinka Odumakin, lawo ni, inu idunnu nla ni ọkunrin naa iba wa lasiko yii bo ba ṣi wa laye, tori Baba Ibeji ni wọn iba maa pa lati saa yii lọ, latari bi iyawo rẹ, Dokita Josephine Okei-Odumakin ṣe bi ibeji lanti-lanti laarin ọsẹ to kọja yii s’Amẹrika, ki i tun ṣe ibeji lasan o, ọmọkunrin kan, ọmọbinrin kan, l’Eledua fi ta wọn lọrẹ.
Atẹjade ti Iya Ibeji ọhun fi lede lopin ọsẹ yii sọ pe ọjọ Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹwaa yii, ni iṣẹlẹ ayọ abara tintin naa waye, ti aya Odumakin feekun ọtun kunlẹ, to si fi tosi dide, pẹlu awọn ẹdunjọbi ọba ọmọ, ejirẹ ara Isokun lọwọ rẹ.
Joe sọ pe ṣaka lara da o, o ni ko si iṣoro kankan foun ati awọn ibeji naa, alaafia ni gbogbo wọn wa. O tun sọ pe niṣe niṣẹlẹ ayọ naa mu ala ati erongba ọkọ oun, Yinka, ṣẹ, nigba to wa laye, o sọ foun pe o wu oun lati bi ọmọ kan to maa ba oun jẹ orukọ.
Ọdun 2000, ọdun kẹta lẹyin igbeyawo wọn, ni tọkọ-taya yii bimọ wọn akọbi, ọmọbinrin, ti wọn sọ ọ ni Joe, orukọ iya ẹ. Wọn bimọ keji, ọmọkunrin, lọdun 2003, wọn si sọ ọmọ naa ni Abraham, ni iranti Oloogbe Abraham Adesanya, Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre nigba yẹn.
Ọdun mejidinlogun lẹyin naa ni ọlẹ ayọ tun sọ ninu iyawo Yinka Odumakin yii, ti wọn si fi oyun naa bi ibeji, bo tilẹ jẹ pe Baba ibeji naa ko si laye mọ, ọjọ kẹta, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii larun Korona gbe ọkunrin naa ṣanlẹ, to si mu ẹmi rẹ lọ lojiji.