Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ko le pẹ rara ti awọn ọkunrin meji yii, Edehikenna Daniel Stanley ati Ṣẹgun Tọpẹ, yoo fi foju bale-ẹjọ, nitori ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti wọn ti mu wọn nibi ti wọn ti n ja ileeṣẹ kan lole ti paṣẹ pe ki wọn tete ko wọn lọ si kootu lati ṣalaye ẹnu wọn.
Ọgbọnjọ, oṣu kẹwaa, lọwọ ba awọn mejeeji, lasiko ti wọn n jale lọwọ ni nnkan bii aago mẹta oru, nileeṣẹ kan ti wọn pe ni Park Company, to wa l’Ọta, nipinlẹ Ogun .
Alukoro ọlọpaa Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, to ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ, sọ ọ di mimọ pe awọn kan ni wọn pe teṣan ọlọpaa Onipaanu, l’Ọta, pe awọn ole ti wọ ileeṣẹ naa, wọn ti ko awọn ọlọdẹ to n ṣọ ibẹ ni papamọra, wọn si ti n ji awọn nnkan nileeṣẹ ọhun lọ.
Eyi ni CSP Bamidele Job ti i ṣe DPO teṣan naa fi ko awọn ikọ rẹ lẹyin lọ sibẹ. Bi wọn ti dọhun-un ti awọn ẹlẹgiri to n jale naa ri wọn ni wọn ti ka a nilẹ, wọn bẹrẹ si i sa lọ. Awọn ọlọpaa naa bẹrẹ si i le wọn, wọn si ri awọn mejeeji mu.
Batiri tawọn onileeṣẹ nla-nla maa n lo lawọn meji naa ti ji kalẹ, awọn ọlọpaa gba a lọwọ wọn. Bakan naa ni wọn tun gba ibọn onike ti wọn fi dẹruba awọn ọlọdẹ to n ṣọ ibẹ, ti wọn si fi halẹ mọ wọn pe awọn yoo pa wọn.
Bi wọn ti mu wọn naa ni CP Lanre Bankọle ti paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ sẹka iwadii iwa ọdaran nipinlẹ Ogun, lẹyin naa ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.