Jọkẹ Amọri
Lati daro awọn eeyan to padanu ẹmi wọn nibi ile alaja mọkanlelogun to da wo ni ilu Ikoyi, nipinlẹ Eko, Gomina Bababjide Sanwoolu ti kede ọjọ mẹta lati fi daro awọn to ku naa, bẹẹ lo ni asia ilẹ wa yoo wa ni ilaji kaakiri ipinlẹ Eko fun awọn ọjọ yii.
Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna feto iroyin, Gbenga Ọmọtọṣọ, fọwọ si lo ti sọ eleyii di mimọ ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Sanwoolu ni gbogbo asia ilẹ wa ni wọn yoo ta de idaji kaakiri awọn ileeṣẹ ijọba ati ti aladaani, bẹẹ ni ko si ni i si oun so gbogbo awọn iṣẹ to yẹ ki oun ṣe rọ laarin ọjọ mẹtẹẹta naa.
Bakan naa lo tun kẹdun pẹlu awọn mọlẹbi to padanu awọn eeyan wọn lasiko iṣẹlẹ naa.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kin-in-ni, oṣu kọkanla yii, ni ijamba buruku naa ṣẹlẹ, nibi ti ile alaja mọkanlelogun ti wo, to si ṣeku pa ọpọlọpọ eeyan.
Eeyan bii mejilelọgbọn ni wọn lo ti padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ naa, ti wọn ko si ti i dawọ iṣẹ duro lati ri i pe wọn yọ awọn to ku labẹ awoku ile ọhun.
Bakan naa ni Sanwoolu ṣabẹwo si awọn ti ori ko yọ ninu ijamba naa, ṣugbọn ti wọn fara pa ni ọsibitu ti wọn wa.
Ẹẹmẹta ọtọọtọ ni gomina ti ṣabẹwo sibi iṣẹlẹ naa.