Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Nitori ẹsun jibiti, akọwe ile-ẹjọ ri ẹwọn ọdun meje he n’llọrin
Ile-ẹjọ giga kan to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo ti sọ Akọwe ile-ẹjọ naa, Arabinrin Fatimoh Olatunji, sẹwọn ọdun meje pẹlu isẹ aṣekara, fẹsun pe o lu gbajumọ oniṣowo kan, Sherifat Oloriẹgbẹ, ni jibiti apo irẹsi ẹẹdẹgbẹta bagi to to miliọnu mẹwaa lorukọ ile-ẹjọ giga naa.
Tẹ o ba gbagbe, ọdun 2017, ni wọn kọkọ wọ Ọlatunji lọ si kootu ibilẹ kan niluu Ilọrin, fẹsun jibiti lilu ọhun, ṣugbọn to rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, tori pe awọn dijọ dowo pọ pẹlu Oloriẹgbẹ ni.
Nigba ti Onidaajọ Ishiaq, tile-ẹjọ giga ọhun, n gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni olujẹjọ naa jẹbi ẹsun jibiti ti wọn fi kan an, adajọ ni ko lọọ ṣẹwọn ọdun meje, ko si tun san miliọnu meje naira owo ‘gba ma binu’ fun olupẹjọ, Oloriẹgbẹ.
Agbẹjọro olujẹjọ naa, Toyin Ọnọọlapọ, ti ni awọn yoo gba ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lọ.