Jọkẹ Amọri
Ọkan ninu awọn agunbanirọ to n sin ijọba nileeṣẹ Fourscore, Zainab Sanni, naa wa ninu awọn to ku sinu ile alaja mọkanlelogun to da wo lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Awọn mọlẹbi ọmọbinrin naa ni wọn kede ọrọ yii lori ẹrọ agbọrọkaye pe ọmọbinrin naa ti ku gẹgẹ bi iweeroyin Punch ṣe sọ.
Bo tilẹ jẹ pe lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lawọn eeyan ti n gbe e kiri pe ọmọbinrin naa ti ku, ṣugbọn ọkan ninu awọn to mọ ọn dahun pe ko ti i ku, o wa nileewosan ni.
Ṣugbọn awọn ẹbi rẹ ti fidi rẹ mulẹ bayii pe Zainab ti ku pẹlu bo ṣe gbe ikede naa sori ẹrọ ayelujara.
Ipinlẹ kan ni Oke-Ọya la gbọ pe wọn gbe e si lati sin ijọba, ko too waa yi i pada si ipinlẹ Eko, ti wọn si gba a si ileeṣẹ Fourscore, nibi to ti n ṣiṣẹ titi ti iṣẹlẹ ile to wo naa fi ṣẹlẹ, to si mu ẹmi rẹ lọ.