Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori iku Abilekọ kan, Yẹmi Ajayi, ẹni ti wọn ba oku rẹ ninu yara rẹ loru ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ninu ile to n gbe laduugbo Abusọrọ, Ijọka l’Akurẹ.
ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu araadugbo kan ta a forukọ bo lasiiri pe niṣe ni wọn gun obinrin naa lọbẹ pa mọ ori bẹẹdi laarin oru ọjọ Aiku, Sannde, mọju ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Ọmọ iya yii to jẹ obinrin lo ji laaarọ kutukutu ọjọ naa, to si dide lati lọọ ba iya rẹ ki wọn le jọ gbadura pọ gẹgẹ bii iṣe wọn laaarọ, ṣugbọn ti ko ri i nibi to ro pe o sun si.
Nibi to ti n wa a kiri lo ti ri oku iya rẹ ninu agbara ẹjẹ lori bẹẹdi, ninu yara mi-in, ti ẹni to ṣiṣẹ ibi ọhun si ko ọpọlọpọ aṣọ le e lori.
Igbe ọmọbinrin yii lawọn araadugbo gbọ ti wọn fi sare lọ sibẹ lati foju ara wọn ri ohun to n ṣẹlẹ.
O ni pupọ ninu awọn eeyan ni wọn sa pada, tawọn mi-in si n ṣomi loju poroporo nigba ti wọn ri i bi wọn ṣe pa abilekọ naa nipakupa. Ọna marun-un ọtọọtọ lo ni ẹni ọhun ti gun un lọbẹ nikun.
O ni kayeefi nla niṣẹlẹ naa ṣi n jẹ fun awọn nitori pe ọdun kẹta ree ti amookunsika kan waa pa ọkan ninu awọn ọmọ oloogbe naa mọ inu ile kan naa ti wọn pa obinrin ọhun si.