Faith Adebọla
Ijamba afẹfẹ to bu gbau ti fẹmi ọpọ eeyan ṣofo l’Opopona Ọjẹkunle, lagbegbe Papa Ajao, nipinlẹ Eko, tawọn mi-in si fara pa yannayanna.
Nnkan bii aago mẹjọ aabọ owurọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, la gbọ pe iṣẹlẹ yii waye, nigba tawọn aladuugbo ṣadeede gbọ iro ibugbamu gaasi naa, ti kaluku si bẹrẹ si i sa kijokijo.
Ba a ṣe gbọ, awọn eeyan ṣi wa labẹ awoku ile to ṣẹlẹ nigba ti ibugbamu naa waye, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ajọ to n ri si ọrọ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, ati awọn panapana ti n ṣiṣẹ takuntakun lagbegbe naa lati doola ẹmi wọn.
Bakan naa ni wọn ti ko oku awọn to doloogbe lọọ si mọṣuari ọsibitu ijọba ni Mushin.
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, sọ pe foonu ti wọn gbe sitosi ibi ti afẹfẹ gaasi wa lo fa ina naa.