Jọke Amọri
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni wọn ṣi n wa ọkunrin adẹrin-in poṣonu nni, Ahmed Gafar, ti gbogbo eeyan mọ si Cute Abiọla.
Gẹgẹ bi ọkan ninu awọn oṣere ẹgbẹ ẹ, Biọdun Ọkẹowo, ti gbogbo eeyan mọ si Ọmọbutty ṣe gbe iwe kan ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ Abiọla, iyẹn The Management of THE CUTE ABIỌLA ENTERTAINMENT LTD, gbe jade, si ori ikanni Instagraamu rẹ, o ṣalaye pe ‘Ahmed Gafar ti gbogbo eeyan mọ si Cute Abiọla kuro ni ile rẹ, o si lọ si ọọfiisi rẹ ni Navy Town, ni nnkan bii aago mẹfa aarọ ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kọkanla ọdun 2015 yii, o si de ibi iṣẹ ni nnkan bii aago meje aarọ. Nigba to debi iṣẹ, o pe iyawo ati awọn alabaaṣiṣepọ rẹ pe oun ti de ibi iṣẹ o.
‘Ṣugbọn latigba naa ni iyawo ati awọn eeyan rẹ ti n pe foonu rẹ, ṣugbọn ti ko lọ. Latigba to ti pe iyawo ati awọn to sun mọ ọn pe oun ti debi iṣẹ ni ko ti pada wale, ti wọn ko ti gburoo rẹ mọ.
‘Ibẹrubojo bi wọn ko ṣe ri ọmọkunrin yii lo jẹ ki iyawo Abiọla atawọn eeyan rẹ kan gba ibi iṣẹ rẹ lọ lati beere ohun to ṣẹlẹ. Ṣugbọn awọn ọga to wa nibẹ ko sọ ohunkohun fun iyawo Abiọla tabi ẹnikẹni, wọn ko si mọ ohunkohun nipa ọmọkunrin naa.
‘Lẹyin-o-rẹyin ni wọn yọ ọ gbọ pe wọn ti ti ọmọkunrin naa mọle ninu atimọle awọn ọmọ oju ogun omi latigba to ti debi iṣẹ titi di asiko ti mo n kọ ọrọ yii jade, ti wọn ko fun un lounjẹ, wọn ko si sọ igba ti wọn maa tu u silẹ ninu ahamọ ti wọn ti i mọ.
‘Eyi to ba ni lọkan jẹ ninu ọrọ naa ni pe ko sẹnikankan to jade lati sọ pe ẹṣẹ bayii lo ṣẹ, wọn kan ti i mọlẹ ni, wọn ni aṣẹ lati olu ileeṣẹ ọmọ ogun oju omi ni wọn fi ti i mọle.
Iṣẹlẹ yii ti mu ki ọkan iyawo rẹ poruru, ti wahala nla si ti de ba a nitori Abiola ni aisan ọgbẹ inu, bi wọn ko si ṣe fun ẹni ti ọgbẹ inu n da laamu lounjẹ jẹ ohun ti o ba yan lọkan jẹ lai naani ipo to wa ati ohun to ṣeeṣe ko ṣẹlẹ si i ilera Cute Abiọla
‘Eyi la fi n pe fun iranlọwọ lati ọdọ Aarẹ ilẹ wa, Igbakeji Aarẹ, Ọlori awọn aṣofin agba ati Olori awọn aṣoju-ṣofin ati gbogbo awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ba wa pe akiyesi ileeṣẹ oju omi ilẹ wa pe ki wọn tu Abiọla silẹ ti wọn ko ba le ṣalaye ẹṣẹ to ṣẹ gan-an to fi dẹni ti wọn n ti mọle.’
Titit di ba a ṣe n sọ yii, wọn ko ti i tu oṣere naa silẹ.