Ọwọ ajọ sifu difẹnsi tẹ awọn afurasi to n ji epo gbe n’Igbọkọda

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lori ẹsun biba ọpọlọpọ agba epo rọbi ni ikawọ wọn, awọn afurasi bii mẹjọ lọwọ ajọ sifu difẹnsi ipinlẹ Ondo tẹ lagbegbe Igbọkọda lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii.

Alakooso agba fun ajọ sifu difẹnsi nipinlẹ Ondo, Dokita Hammed Abọdunrin, lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin nipasẹ Alukoro wọn, Olufẹmi Ọmọle.

O ni awọn eeyan kan ni wọn ta awọn lolobo lori ọkọ oju omi mẹrin tawọn afurasi ọhun fi ko ayederu epo diisu tí wọn lawọn fẹẹ lọọ ko fun ẹnikan.

Ogoji agba epo disu lo ni wọn ko sinu ọkọ oju omi kin-in-ni, ekeji ati ẹkẹta, nigba ti ọkọ oju omi kẹrin ko agba diisu mọkandinlogoji, ti apapọ lita epo ti wọn ba ni ikawọ awọn afurasi ọhun si jẹ igba lita.

Dokita Abọdunrin ni awọn tọwọ tẹ ọhun jẹwọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ lasiko ti wọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo pe ipinlẹ Delta lawọn ti n ko ẹru ofin naa bọ, ati pe ẹnikan ti wọn porukọ rẹ ni Adeyẹmi Ogunkayọde lo ko agba epo ọhun fun awọn.

O ni awọn afurasi ọhun ko ni i pẹẹ foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

 

Leave a Reply